AbdulRazaq ba Etsu Tsaragi yọ f'ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mejidinlaadọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 26, 2023

AbdulRazaq ba Etsu Tsaragi yọ f'ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mejidinlaadọrin


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ba Etsu Tsaragi, Alayeluwa Alaaji Aliyu Abdullahi Kpotwa yọ fun ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ to waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
 
Ninu atẹjade ikini ti gomina gbe jade lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye, gomina ṣapejuwe ọba alaye naa gẹgẹbi aṣiwaju to ṣee tẹle, ẹni to n gba alaafia ati iṣọkan laaye.

O ni kabiyesi yii n fi ojoojumọ wa ifẹ, iṣọkan ati alaafia ilu, to fi mọ idagbasoke ati ilọsiwaju loorekoore.
 
Bakan naa ni AbdulRazaq tun gbe oriyin fun kabiyesi fun ifẹ to n ni si idagbasoke awọn ọdọ lagbegbe rẹ, to si ni ilọsiwaju Tsaragi ti daju.

Bẹẹ lo gbarura ẹmi gigun ati alaafi fun ọba naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI