Wolii Ọṣhọffa to fi majele pa awọn ọmọ aburo rẹ meji lasiko itusilẹ dero Kirikiri l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 8, 2023

Wolii Ọṣhọffa to fi majele pa awọn ọmọ aburo rẹ meji lasiko itusilẹ dero Kirikiri l'Ekoo


Ile-ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Yaba nipinlẹ Ekoo ti sọ pe ki wọn ṣi lọ fi olori ijọ Sẹlẹ kan, Celestial Church of Christ, Alpha and Omega, Ashipa Parish 4, David Ọṣhọffa pamọ sọgba ẹwọn Kirikiri lori ẹsun ipaniyan.
 
A gbọ pe David lo fun awọn ọmọ aburo rẹ meji kan, Michael Agba, ọmọ ọdun mejila ati Mahoklo Agbah, toun jẹ ọmọ ọdun mẹjọ ni majele jẹ, pẹlu ẹtanjẹ wi pe oun fẹẹ le ẹmi okunkun jade lara wọn.
 
Wọn ni agbegbe Sẹmẹ Border to wa ni Badagry, ipinlẹ Ekoo ni ṣọọṣi David wa, nibi lo si ti pa awọn ọmọ naa danu.
 
Agbefọba Thomas Nurudeen to f'oju David ba ile-ẹjọ lori ẹsun mẹta ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu ipaniyan ṣalaye pe niṣe ni wọn ko awọn ọmọ ọhun wa si ṣọọṣi David fun itusilẹ, to si loun yoo yanju iṣoro wọn.
 
Nurudeen sọ pe asejẹ ati agbo buruku kan ni David fun awọn ọmọ naa, pẹlu erongba lati le ẹmi okunkun jade kuro lara wọn, ati pe o mọ pe awọn nnkan naa yoo pa awọn ọmọ wọnyii lara, to si fi iwa aibikita fun wọn.

O l'awọn nnkan naa lo ṣeku pa awọn ọmọ ọhun l'ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹfa, ọdun 2023 ti a wa yii, ẹsun naa to lo tako iwe ofin ọdaran 2015 ti abala 222, to si ni ijiya ninu labala 223.
 
Onidajọ Patrick Nwaka nigba to n sọrọ sọ pe oun ko le gbọ ẹbẹ David nitori pe iwa ọdaju lo wu, ati pe oun yoo duro de ọrọ amọran lati ọdọ ajọ Directorate of Public Prosecutions, fun idi eyi, o ni k'awọn ọlọpaa ṣi lọ fi pamọ s'ọgba ẹwọn Kirikiri titi digba ti igbẹjọ miran yoo tun waye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI