AbdulRazaq ba igbakeji rẹ yọ f'ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọta ọdun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 1, 2023

AbdulRazaq ba igbakeji rẹ yọ f'ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọta ọdun


Bi gbogbo awọn eeyan kaakiri agbaye ṣe n ba igbakeji gomina ipinlẹ Kwara, Kayọde Alabi yọ fun ti ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọta ọdun to pe loke eepẹ lonii, ọjọ kinni, oṣu kẹjọ, ọdun 2023, bẹẹ naa ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ko gbẹyin ninu awọn to n ki i ku oriire.
 
Ninu atẹjade ikini ti gomina fi ranṣẹ lati ọwọ akọwe iroyin ẹ, Rafiu Ajakaye, o ṣapejuwe Alabi gẹgẹ bi igbakeji to ṣee f'ọkan tan, ati ọkan pataki lara awọn to mu ẹgbẹ oṣelu lokukudun.
 
AbdulRazaq ninu atẹjade naa dupẹ gidigidi lọwọ Alabi fun igbarukuti ẹ, ati ifọwọsowọpọ to ni lati jẹ ki iṣakoso rẹ maa lọ bo ti yẹ.
 
Bẹẹ lo dupẹ lori awọn ọrọ amọran to n fun un ni gbogbo igba, paapaa lati ọdun 2019 ti wọn ti jọ n ṣe ijọba bọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI