Awọn akẹkọọ tun bọ s'aye ni Kwara, ẹgbẹrun mẹwaa naira ni wọn yoo maa gba bayii - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 1, 2023

Awọn akẹkọọ tun bọ s'aye ni Kwara, ẹgbẹrun mẹwaa naira ni wọn yoo maa gba bayii


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti buwọ lu sisan owo ti ko din ni ẹgbẹrun mẹwaa naira fun gbogbo awọn akẹkọọ ileewe giga patapata ti wọn jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Kwara, gẹgẹ bi owo iranwọ lori ọwọngogo to n ṣẹlẹ lakoko yii.
 
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye fi sita lonii, ọjọ kinni, oṣu kẹjọ, ọdun 2023, o ni kaakiri ileewe giga to jẹ ti ijọba l'awọn akẹkọọ ti wọn jẹ ọmọ bibi ipinlẹ naa yoo ti lanfaani si owo iranwọ yii.

Ajakaye, ninu atẹjade naa ti jẹ ko di mimọ pe yatọ si awọn akẹkọọ ti wọn yoo jẹ anfaani yii, bẹẹ láwọn ileeṣẹ eleto aabo miran naa yoo tun jẹ anfaani yii, ati pe ileeṣẹ Kwara State Social Investment Programme (KWASSIP) ni yoo ṣagbatẹro eto yii.

Gomina AbdulRazaq fi kun un pe lara awọn iranwọ ti ijọba fẹ maa ṣe f'awọn akẹkọọ ti wọn ti wa ni ipele aṣekagba ni sisan ẹgbẹrun marun-un naira si ẹgbẹrun mẹwaa naira fun wọn.
 
Ọjọgbọn Shehu Raheem Adaramaja, to jẹ alaga Kwara State Universal Basic Education Board (KWSUBEB) la gbọ gbe yoo jẹ alaga igbimọ alabojuto fun eto naa, bẹẹ lawọn aṣoju lati ẹka ileeṣẹ ijọba bii Ministry of Tertiary Institution, bursary department, Ministry of Finance, to fi mọ awọ aṣoju lati inu ẹgbẹ akẹkọọ National Association of Kwara State Students (NAKSS) ati National Association of Nigerian Students (NANS) ni yoo parapọ ṣiṣẹ.
 
Siwaju sii la gbọ pe awọn igbimọ yii yoo ṣi ikanni ayelujara t'awọn akẹkọọ yoo ti maa fi orukọ silẹ lati jẹ anfaani yii, pẹlu awọn iwe ẹri to daju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI