Eeeyan mẹfa pere ni mo ti f'ibọn pa, ẹ dariji mi - Lukmọn, ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun jẹwọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, August 19, 2023

Eeeyan mẹfa pere ni mo ti f'ibọn pa, ẹ dariji mi - Lukmọn, ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun jẹwọ


'O pari' lọrọ ti wọn lo kọkọ jade lẹnu gendekunrin, Lukmọn Shonubi, ẹni ti wọn sọ pe ko n'iṣẹ meji kọja idigunjale, ṣiṣẹ ẹgbẹ okunkun, ati ipaniyan, to si n rawọ ẹbẹ fun idariji.
 
Nibi ode ariya kan la gbọ pe ọwọ palaba Lukmọn, ẹni t'awọn eeyan tun n pe ni Tinny ti segi, lakoko toun pẹlu awọn ọrẹ rẹ fẹẹ da wahala silẹ, paapaa lati da ode ariya naa ru.
 
Wọn ni nigba t'awọn eeyan ri ọwọ ti Lukmọn ati awọn ọrẹ rẹ n gbe, ni wọn ti ranṣẹ s'awọn ọlọpaa, to si jẹ iyalẹnu f'awọn ọlọpaa wi pe ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ ti wọn n wa tipẹ ni.

Bi wọn ṣe mu Tinny de teṣan wọn, ni wọn ti bẹrẹ sii f'ọrọ wa a lẹnu wo, to si jẹwọ pe ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun loun, toun si maa n lo anfaani rẹ lati fi digunjale.
 
O loun ti digun ja ile itaja igbalode kan lole ri, bẹẹ loun ti ja obinrin kan lole pẹlu ibọn lopopona Molipa. O loun gba baagi obinrin pẹlu foonu, to fi mọ ẹgbẹrun lọna ọọdunrun nair.
 
Siwaju si i lo fi kun un pe eeyan mẹfa loun ti pa latigba toun ti bẹrẹ sii ṣe ẹgbẹ okunkun naa.
 
Ọmọlọla Odutọla to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun nigba to n sọrọ ṣalaye siwaju pe b'awọn ọlọpaa ṣe lọ yẹ ile rẹ wo,  ni wọn ba ibọn agbelẹrọ to fi n ṣiṣẹ buruku nibẹ, to si ni iwadii tun ti n lọ lọwọ lori ẹ.
 
Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ wi pe ọga awọn, CP Abiọdun Alamutu ti sọ pe aaye ṣi ṣi silẹ fun gbogbo awọn to ba fẹẹ kuro ninu ẹgbẹ okunkun lati wa si ileeṣẹ ọlọpaa, ki wọn si kede sita, nitori pe ẹni ti ọwọ ba tẹ yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ labẹ ofin orileede Naijiria.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI