Iroyin ti ko dun mọ ẹnikẹni ninu ni bi akẹkọọ fasiti ipinlẹ Ekoo, Lagos State University (LASU) kan, Ademola Ayinla Timothy ṣe padanu ẹmi rẹ sinu ijamba ọkọ to wa lopopona Ṣagamu si Benin, ipinlẹ Ogun.
Nnkan bi aago meje ku iṣẹju mẹẹdogun, Ọjọru tii ṣe Wẹsidee, ọsẹ yii la gbọ pe Ademọla ati awọn meji miran padanu ẹmi wọn.
Tirela Geon ti nọmba idanimọ rẹ jẹ LAR 730 XB ati Lexus SUV ti nọmba idanimọ tiẹ jẹ BDG 979 HD, to fi mọ Toyota Sienna kan ni iroyin fi to wa leti pe wọn kọlu ara wọn.
Ọmọlọla Odutọla to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun nigba to n f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni ikorita Babcock ni ijamba ọhun ti waye.
Agbẹnusọ ọlọpaa naa sọ pe awakọ Lexus naa lo n wa iwakuwa lọ, to si ṣe bẹẹ lọọ kọlu tirela, ko to di pe o gbokiti, ti Sienna naa si lọ kọluu.
O fi kun un pe wọno gbiyanju lati doola ẹmi Ademọla, ṣugbọn to pada gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra ko to de ọsibitu.
No comments:
Post a Comment