Ẹ ba mi dupẹ lọwọ Gomina AbdulRazaq fun anfaani ẹlẹẹkeji to tun fun mi lati ba a ṣiṣẹ papọ - Solace, amugbalẹgbẹ agba pataki - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, August 19, 2023

Ẹ ba mi dupẹ lọwọ Gomina AbdulRazaq fun anfaani ẹlẹẹkeji to tun fun mi lati ba a ṣiṣẹ papọ - Solace, amugbalẹgbẹ agba pataki


Orin ọpẹ lo gba ogbontarigi onimọ nipa iroyin ori ayelujara nni, Ọlayinka Michael Fafoluyi, ẹni t'ọpọ awọn eeyan tun mọ si Solace, nigba ti gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq kede rẹ gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ agba pataki (Senior Special Assistant) lori ọrọ iroyin ori ayelujara ti yoo ba a ṣiṣẹ papọ ni saa keji iṣejọba rẹ.

Solace jẹ amugbalẹgbẹ pataki (Special Assistant, New Media) si Gomina AbdulRazaq ni saa iṣejọba akọkọ, iyẹn laaarin ọdun 2019 si 2023.

Ọjọbọ tii ṣe Tọside, ọsẹ yii ni Gomina AbdulRazaq tun kede Yinka Solace, to si tun fun un ni igbega nidii iṣẹ naa, lori ipa pataki to ko ni saa akọkọ rẹ.
 
Nigba to n fi ẹmi imoore han, Yinka Solace  ni "Idunnu ati ayọ nla lo jẹ fun mi nigba ti mo gba iroyin wi pe Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti yan mi gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ agba pataki (Senior Special Assistant, New Media), o si jọ mi loju gidi.
 
"Tọkantọkan ni mo fi n dupẹ fun anfaani ọtun miran yii lati sin oun ati ipinlẹ wa lapapọ. Mo mọ daju pe itan ko le gbagbe Gomina AbdulRazaq bo ṣe n yan awọno ọdọ s'ipo. Bakan naa ni mo tun n fi asiko yii dupẹ lọwọ awọn ọrẹ mi, alabaṣiṣẹpọ mi ati awọn ikọ mi fun aduroti wọn."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI