Ẹgbẹrun meje ọdaran lọwọ tẹ l'Ondo - Ọga Amọtẹkun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, August 12, 2023

Ẹgbẹrun meje ọdaran lọwọ tẹ l'Ondo - Ọga Amọtẹkun


Ọga agba pata funn ileeṣẹ eto aabo Amọtẹkun n'ipinlẹ Ondo, Adetunji Adelẹyẹ ti sọ ọ sita gbangba wi pe ko din ni ẹgbẹrun meje ọdaran ti ọwọ awọn ti tẹ laaarin ọdun mẹta ti wọn ti da wọn silẹ.
 
Adelẹyẹ sọ pe kaakiri ipinlẹ naa ni awọn ọdaran ti ọwọ tẹ, to si ni awọn ti ko din ni ẹgbẹrun kan aabọ ni wọn ti foju wọn ba ile-ẹjọ, ati pe pupọ ninu wọn ni wọn ti jẹ iyan wọn n'iṣu.
 
Ọga agba naa lo sọrọ yii lakoko to n ba ikọ aṣojukọroyin ipinlẹ Ondo, iyẹn Correspondents’ Chapel to jẹ ọkan gboogi lara awọn ẹka to di ẹgbẹ awọn akọroyin mu, lori eto ti wọn pe ni “The Platform.”
 
Nibẹ lo ti sọ pe oriṣiriṣi aṣeyọri l'awọn ti ṣe nipa gbigbogun ti iwa ọdaran laarin ilu ati ipinlẹ naa.
 
Siwaju siii lo jẹ ko di mimọ pe akitiyan awọn lo dawọ wahala to n ṣẹlẹ laaarin awọn agbẹ ati Fulani darandaran ku
 
O ni laaarin ọdun meji si asiko yii, wahala ati ipenija naa ti dinku ni ida marundinlọgọrun-un, to si ni alaafia ti n jọba bayii laarin awọn agbẹ ati Fulani darandaran.
 
Bakan naa lo sọ pe ajọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ naa tun ṣiṣẹ takuntakun nipa fifun wọn l'awọn ohun amuyẹ nipa iwa ijinigbe, to si l'awọn ṣe aṣeyọri to pọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI