Peter ta ọmọ-ọmọ rẹ danu, lo ba fi owo gba ṣọọbu, o tun ra ọja si ṣọọbu ọhun l'Ọyọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, August 13, 2023

Peter ta ọmọ-ọmọ rẹ danu, lo ba fi owo gba ṣọọbu, o tun ra ọja si ṣọọbu ọhun l'Ọyọ


Ọrọ buruku toun tẹrin nigba ti wọn sọ pe baale ile, ẹni ogoji ọdun kan, Peter Chukwuka ta ọmọ-ọmọ rẹ to jẹ ọmọ oojọ ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin (N700,000) naira, to si lọ fi owo rẹ gba ṣọọbu, to tun ra ọja sinu ṣọọbu ọhun pẹlu.
 
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ lo fi oju Peter han f'awọn akọroyin nipinlẹ naa laipẹ yii, nibi ti Peter ti jẹwọ bi ọrọ ọhun ṣe ri.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ilu Ọyọ n'ipinlẹ Ọyọ ni Peter n gbe, ṣugbọn ipinlẹ Abia lọhun ni wọn lo lọ ta ọmọ naa danu si.
 
Ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọmọwe Adebọla Hamzat nigba to n sọrọ sọ pe Peter ati awọn ẹmẹwa rẹ marun-un ti wọn jọ ṣiṣẹ buruku naa lọwọ palaba wọn ti segi.
 
Yatọ si awọn wọnyi, ileeṣẹ ọlọpaa tun f'oju awọn marundinlogoji miran han lori ẹsun bii idigunjale, ijinigbe, ẹgbẹ okunkun ati jibiti loriṣiriṣi.
 
Ninu ọrọ ọga ọlọpaa, o ni ọjọ kẹwaa, oṣu keje, ọdun 2023 ni Peter gba ẹbi ọmọ rẹ, Sarah Chukwuka, ọmọ ọdun mẹẹdogun to wa ninu oyun, bo si ṣe gbe ọmọ naa jade, lo ti gba ipinlẹ Abia lọ lati ta a danu fun obinrin kan to n ṣoowo ọmọ.
 
Wọn ni latigba ti olobo ti ta awọn ni iwadii ti bẹrẹ, to si jẹ ilu Ibafo, ipinlẹ Ogun lọwọ ti tẹ Peter, iyẹn nibi to sapamọ si.
 
Ninu ifọrọwerọ ti wọn ṣe fun Peter lo ti jẹwọ pe ẹtanjẹ loun fi gba ọmọ naa kuro lọwọ ọmọ oun. O loun sọ pe oun fẹ lo gbe ọmọ naa fun ẹnikan to le tọju rẹ daadaa, ti ko si nii ku.
 
O ni boun ṣe gba ọmọ yii loun gba ilu Obehi to wa ni Okwa West, ipinlẹ Abia lọ, nibi toun ti ta a ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin naira.
 
Siwaju sii ni ọga ọlọpaa naa jẹ ko di mimọ pe iwadii t'awọn tun ṣe lọwọ ti tẹ obinrin kan to ni ileeṣẹ ti wọn ti n ṣoowo ọmọ naa, Popoọla Nwamaka Bunmi, ẹni ọdun mẹtadinlaadọta ati awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ bii Chinwedu Peter, ẹni ọdun marundinlọgbọn; Chidinma Blessing, ẹni ọdun marundinlọgbọn; Chukwu Christopher, ẹni ọdun mọkandinlaadọta; ati Favour Ogadinma, toun jẹ ẹni ọdun mejidinlọgbọn.
 
O ni oriṣiriṣi iwe ti wọn fi n ta ati ra ọmọ ọlọmọ l'awọn ri gba lọwọ wọn, to si ni idajọ ododo yoo waye lẹyin t'awọn ba foju wọn ba ile-ẹjọ.
 
Nigba to n sọrọ, Peter sọ pe “Mo wa lakolo ọlọpaa nitori ọmọ-ọmọ mi ti mo ta. Aṣiṣe ni ọmọ mi fi loyun, to si bi ọmọ naa. Ṣugbọn bi nnkan ṣe ri lorileede Naijiria lasiko yii lo fa iṣẹ ati oṣi to n ba mi ja.
 
“Mi o le da tọju ọmọ mi ati ọmọ rẹ, idi ree ti mo fi gba ọmọ naa lọ ta danu si ipinlẹ Abia. Ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin naira ni mo ta a. Ara iyawo mi ko ya, oun naa si mọ nipa ohun to ṣẹlẹ yi. Igba akọkọ mi ree.
 
“Aburo mi (Favour Chukwu) lo n ba obinrin ti mo ta ọmọ naa fun ṣiṣẹ ọmọ ọdọ. Nipasẹ rẹ si ni mo ṣe mọ ọn. Ọmọ ọmọ mi ko ni baba. Ni bayii, ọwọ ti tẹ mi, mo mọ pe mo ti ṣe aṣiṣe, Ọlọrun nikan si lo le ko mi yọ.
 
“Mo fẹ ki ijọba ran mi lọwọ nitori pe mi o mọ-ọn mọ ṣe e. Owo ti mo gba, mo fi gba ṣọọbu, mo si ra ọja sinu ẹ. Mo fẹẹ bẹrẹ sii ta ọja ni.”
 
Ọmọ naa to bimọ yii, Sarah Chukwu, nigba toun naa n sọrọ sọ pe “Ọmọ ọdun mẹẹdogun ni mi, nigba ti mo loyun, mama sọ pe ki n lọ yọ ọ danu, mo si ni rara, wi pe mo maa bii ni. Ọjọ kẹwaa, oṣu keje, ọdun yii ni mo bimọ naa. Ọjọ kẹji ni baba mi wa, wọn lawọn ni obinrin kan to le ba wa tọju ọmọ naa fun ọdun meji ko to di pe wọn da a pada.
 
“Mo gba si wọn lẹnu, nitori pe mọ ṣi ni ipinnu lati pada sileewe, mi o mọ pe niṣe ni baba mi fẹẹ ta ọmọ naa. Kilaasi kẹfa ni mo wa nile-ẹkọ alakọbẹrẹ. Ṣagamu ni ẹni to fun mi loyun n gbe. O maa n mu ọti ai siga. Igba ti mo loyun fun un, o loun yoo tọju mi.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI