Ẹkundayọ ji foonu awọn akẹkọọ, l'adajọ ba juu sẹwọn ọdun kan l'Ekiti - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, August 5, 2023

Ẹkundayọ ji foonu awọn akẹkọọ, l'adajọ ba juu sẹwọn ọdun kan l'Ekiti


Adajọ ile ẹjọ Majisireeti to wa niluu Ikere-Ekiti, Onidajọ Dọtun Ọmọtẹyẹ ti ju gendekunrin, ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Emmanuel Ẹkundayọ sẹwọn ọdun kan gbako pẹlu iṣẹ aṣekara lori ẹsun ole jija.
 
Foonu ti wọn lo jẹ ti awọn akẹkọọ ile-ẹkọ Bamidele Olumilua University of Education, Science and Technology, Ikere-Ekiti (BOUESTI) ni wọn sọ pe Ẹkundayọ ji.
 
Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu keje, ọdun 2023 la gbọ pe ọwọ tẹ Ẹkundayọ lasiko idanwo saa akọkọ ile-ẹkọ naa.
 
Wọn ni niṣe ni foonu awọn akẹkọọ poora lakoko idanwo naa, eyi ti wọn n ṣe lọwọ ninu gbọgan ile-ikawe ti wọn pe ni Library Lecture Theatre, ti wọn si l'awọn to wa nibẹ yẹ baagi awọn akẹkọọ wo, ko to di pe wọn ba a ninu baagi Ẹkundayọ.
 
Gbara ti wọn ti foju rẹ ba ile-ẹjọ lo ti gba wi pe oun jẹbi, ẹsun ole jija ti wọn fi kan oun, ati pe ki wọn ṣiju aanu wo oun.
 
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Ọmọtẹyẹ paṣẹ pe ki Ẹkundayọ lọ fi ẹwọn ọdun pere gbara, tabi ko lọ san owo itanran ti yoo rọpọ ẹwọn rẹ.
 
Alakoso eto ofin nile-ẹkọ naa, Amofin Busuyi Jayeọba, nigba to n sọrọ lori idajọ yii sọ pe ohun to dara ni, ati pe idajọ naa yoo kọ awọn yooku to fẹ gbe iru igbesẹ ọhun lẹkọọ, nitori pe awọn ko nii gba iwa ọdaran laaye ninu ọgba ile-ẹkọ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI