Abdulai fipa ja ibale ọmọ ara adugbo, ọmọ ọdun mẹta n’Ikorodu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, August 5, 2023

Abdulai fipa ja ibale ọmọ ara adugbo, ọmọ ọdun mẹta n’Ikorodu


Pẹlu ẹsun ti wọn fi kan Abdulai Lawal, ẹni ogoji ọdun ti wọn sọ pe ko niṣẹ gidi kan lọwọ lagbegbe Ikorodu, ipinlẹ Ekoo yii, afaimọ ni ko ma jẹ ẹwọn ni yoo ti pada lo igbesi aye rẹ.
 
Ẹsun wi pe Abdulai f'ipa ja ibale ọmọ ọdun mẹta, to jẹ ọmọ ara adugbo ni wọn fi kan Abdulai niwaju ile-ẹjọ Majisireeti to wa niluu Ikorodu l'Ọjọbọ tii ṣe Tọside, ọsẹ yii.
 
Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, wọn ni iwaju ita ni ọmọdebinrin naa ti n ṣere iyẹpẹ lọwọ, ko to di pe Abdulai pe e, to si gbe e wọnu ile.
 
Ko ju bi iṣẹju meloo kan lọ ni wọn sọ pe iya ọmọ naa jade sita lati wo ọmọ rẹ nibi to ti n ṣere, ṣugbọn ti ko ri i, eyi lo jẹ ko bẹrẹ sii wa a kaakiri.
 
Wọn ni bo ṣe n pariwo ọmọ naa, ni awọn miran naa n ba a pe e, ko to di pe ọmọ yii jade sita ninu yara Abdulai pẹlu ẹjẹ to n da lati abẹ rẹ.
 
Ariwo ikunlẹ abiyamọ ni wọn sọ pe obinrin naa pa, ti awọn eeyan fi gba a lamọran lati lọ fi to ọlọpaa leti.
 
Agbefọba Ọlawunmi Ọṣinbajo to fẹsun kan Abdulai niwaju Onidajọ A.B Olagbegi-Adelabu ṣalaye pe ọjọ karundinlọgbọn, oṣu keje, ọdun ti a wa yii ni ọkunrin naa hu iwa buruku naa.

Ọṣinbajo lo jẹ ka mọ pe agbegbe ti wọn n pe ni Agric to wa niluu Ikorodu, ipinlẹ Ekoo ni iṣẹlẹ ọhun ti waye lọjọ naa.
 
O ni niṣe ni Abdulai n laagun yọbọ bi ohun mimu ẹlẹrindodo to ti pẹ ninu amohuntutu, iyẹn Firisa (Freezer) nigba t'awọn eeyan rii, to si ni wọn ti gbe ọmọ naa lọ si ọsibitu fun ayẹwo, koda, ti wọn tun ṣi n tọju rẹ lọwọ.

Nibẹ lo ti sọ pe ẹsun toun fi kan Abdulai tako iwe ofin ọdaran t'ipinlẹ Ekoo, tọdun 2015, to si ni ijiya ninu.
 
Onidajọ Ọlagbegi-Adelabu, ti wa a paṣẹ wi pe ki wọn ṣi lọ fi Abdulai pamọ sọgba ẹwọ Kirikiri titi di ọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan, ọdun yii ti igbẹjọ yoo ti waye, pẹlu bo ṣe l'awọn yoo duro de itọni lati ọdọ ajọ DP, iyẹn Directorate of Public Prosecutions (DPP), ẹka t'ipinlẹ Ekoo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI