Igbaniwọle sile ẹkọ UBEC Model Smart bẹrẹ lẹkunrẹrẹ ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 15, 2023

Igbaniwọle sile ẹkọ UBEC Model Smart bẹrẹ lẹkunrẹrẹ ni Kwara


Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede sita pe eto igbaniwọle si ile ẹkọ igbakode ti UBEC Model Smart School to wa lagbegbe Adeta, niluu Ilọrin ti bẹrẹ lẹkunrẹrẹ.

Ninu atẹjade ti alakoso ile ẹkọ naa, Ọmọwe Arabinrin Idayat Bọlanle Lawal fi sita lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii lo ti jẹ ko di mimọ pe eto ìforúkọsílẹ naa ti bẹrẹ fun saa ikẹkọọ ọdun 2023 si 2024.

Ọmọwe Lawal ni ọjọ kẹrinla, oṣu kẹjọ, ọdun 2023 ni eto iforukọsilẹ naa bẹrẹ lori ikanni ayelujara ti ile ẹkọ ọhun, to si ni yoo pari lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2023.

Lẹyin iforukọsilẹ ni wọn sọ pe wọn yoo lẹ orukọ awọn to ba peregede lati jokoo fun idanwo si ẹnu ọna abawọle ile ẹkọ naa, iyẹn l'ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejilelogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2023.

Idanwo igbaniwọle ni wọn sọ pe yoo waye l'Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kerinlelogun, oṣu kẹjọ ni deede agogo mẹsan owurọ.

Lara awọn nnkan t'awọn akẹkọọ yoo si mu dani lọjọ naa ni awọn ohun ikọṣẹ, to fi mọ ẹda fọọmu igbaniwọle wọn (Photocopy of printed admission form)

Awọn miran ni;
For JSS1, state entrance exams card is required (I.e Pink, blue or green card).
Promotion exams report card is required for JSS 2, Primary 1, 2, 3, 4, and Pre-prinary class ECCDE( ECCDE if available)

Lati fi orukọ silẹ, ẹ lọ si ikanni 

b. Click on UBEC Model Smart School Registration
c. .Fill the form appropriately 
d. .Click on submit
e. .It displays a printout page 
f. .Click on print to print the page.
6. Successful candidates are expected to resume for 2023/2024 academic session on Monday 18th September, 2023.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI