AbdulRazaq kẹdun iku Latinwọ, gomina tẹlẹri ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 15, 2023

AbdulRazaq kẹdun iku Latinwọ, gomina tẹlẹri ni Kwara


Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe gomina tẹlẹri ni ipinlẹ Kwara, Captain Salaudeen Adebọla Latinwọ ti jade laye, eyi to ṣi n ṣe awọn eeyan ni kayeefi titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.

Gomina Abdulrahman Abdulrazaq ti wa a ba gbogbo ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa, paapaa awọn araalu Ọffa kẹdun iku oloogbe Latinwọ, ẹni to ti figba kan ri jẹ alakoso ipinlẹ naa lakoko ologun

AbdulRazaq ni lara awọn to sọ iṣẹ ologun ori ofurufu di irọrun ni Latinwọ, ẹni to darapọ mọ iṣẹ Nigeria Air Force lọdun 1963.

O ni lati ipo cadet ti wọn fi gba a wọle, lo ti ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe o di olori ipinlẹ naa lakoko oṣẹjọba Muhammadu Buhari.

Ninu atẹjade ti gomina fi sita lopin ọsẹ to kọja, o ni adanu nla ni iku Latinwọ jẹ fun ipinlẹ naa, nitori pe lara ipa rere to fi le'lẹ l'awọn n tẹle.

O wa gbadura pe ki Ọlọrun tẹ si afẹfẹ rere, ko si duro ti awọn mọlẹbi ti fi silẹ lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI