Ipinlẹ Ekoo ni Samuel ti pa iyawo ẹ, Ijẹbu-Igbo nibi to lọ farapamọ si lọwọ ti tẹ ẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, August 18, 2023

Ipinlẹ Ekoo ni Samuel ti pa iyawo ẹ, Ijẹbu-Igbo nibi to lọ farapamọ si lọwọ ti tẹ ẹ


Ọwọ ileeṣẹ eto Amọtẹkun n'ipinlẹ Ogun ti tẹ baale ile, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn kan, Adebiyi Samuel, lori ẹsun wi pe o lu iyawo ẹ, Serah Ogungbe pa.
 
Samuel ni iroyin fi to wa leti pe ọwọ tẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii lakoko t'awọn ẹṣọ aabo Amọtẹkun naa n ṣiṣẹ kaakiri.
 
A gbọ pe agbegbe Lẹkki Phase II to wa n'ipinlẹ Ekoo ni Samuel ti pa iyawo ẹ, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn naa, to si na papa bora lọ sagbegbe kan niluu Ijẹbu-Igbo, ijọba ibilẹ Ariwa Ijẹbu, ipinlẹ Ogun, iyẹn nibi tọwọ palaba rẹ ti segi.
 
Ninu atẹjade ti igbakeji oga agba Amọtẹkun nipinlẹ naa, Aina Oluwakayọde fi sita l'Ọjọbọ tii ṣe Tọside, o ni Samuel lo jẹwọ funra rẹ.
 
Oluwakayọde wa fi kun ọrọ rẹ wi peawọn yoo fa a le olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun to wa ni Eleweran, Abẹokuta lọwọ fun itẹsiwaju iwadii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI