Ko pẹ ti Emmanuel tẹwọn de, lo tun lọ ji foonu n'Ikirun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, August 18, 2023

Ko pẹ ti Emmanuel tẹwọn de, lo tun lọ ji foonu n'Ikirun


Amọtẹkun n'ipinlẹ Ọṣun ti rọwọ to gendekunrin, ẹni ọgbọn ọdun kan, Emmanuel Popoola to ji foonu niluu Ikirun, toun naa si jẹwọ pe ogbologbo loun nidi iṣẹ ole jija, paapaa jiji foonu.
 
Ọmọ bibi ilu Modakẹkẹ naa ni iroyin fi to wa leti pe ko pẹ to de lati ọgba ẹwọn ti wọn juu si, lọwọ tun tẹ ẹ lori ẹsun kan naa.
 
Ọgagun Bashir Adewinmbi to jẹ ọga agba Amọtẹkun n'ipinlẹ Ọṣun, nigba to n f'oju Emmanuel han l'Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ yii, o sọ pe ọmọkunrin naa ko n'iṣẹ meji ju ko maa ji foonu oni foonu lọ.
 
Adewinmbi sọ pe ẹnikan lo wa fi ẹjọ sun pe wọn ji foonu oun, to si ni iwadii bẹrẹ loju ẹsẹ.
 
O ni bọwọ ṣe tẹ ọmọ bibi ilu Ikirun, ijọba ibilẹ Modakẹkẹ naa lo ti bẹrẹ sii ka boroboro, to si jẹwọ pe oun ti lọ sẹwọn ri lori ẹsun jiji foonu, ati pe ko pẹ toun jade.
 
Siwaju sii ni Adewinmbi fi ye wa pe nibi ti Emmanuel ti fẹẹ ta awọn foonu to jigbe lọwọ ti tẹ ẹ.
 
Lara awọn nnkan ti wọn gba lọwọ ẹ ni SIM Card mejila ọtọọtọ, foonu Infinix Hot kan, foonu Techno Pop 3 kan, foonu Techno Spark kan ati ATM.
 
Ọga agba naa jẹ ko di mimọ pe awọn ti fa a le awọn ọlọpaa lọwọ fun itẹsiwaju iwadii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI