Mi o mọ ẹmi to gbe mi wọ - Adewale to f'ipa ja ibale ọmọ ọdun mẹta sọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, August 17, 2023

Mi o mọ ẹmi to gbe mi wọ - Adewale to f'ipa ja ibale ọmọ ọdun mẹta sọrọ


Adewale Mustapha, ọmọ ọdun mejilelogun kan ti wọn f'ẹsun kan wi pe o f'ipa ja ibale ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹta ti sọ pe oun ko mọ ẹmi buruku to gbe oun wọ lakoko toun n huwa buruku naa.


Nnkan bi aago mẹta kọja ogun iṣẹju, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 2023 ni wọn sọ pe iya ọmọ naa sọ fun Adewale lati maa ba a ṣọ ọ, nitori toun fẹẹ sare jade.
 
Igba ti obinrin naa yoo fi pade de, lo ṣakiyesi pe nnkan ti ṣe ọmọ oun, ti ọmọ naa si ṣalaye ohun to ṣẹlẹ.
 
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Yẹmisi Ọpalọla fi sita, o ni gbara ti obinrin naa ti gbọ pe Adewale lo f'ipa gba aṣọ iyi lara ọmọ oun, lo ti gba teṣan ọlọpaa lọ lati fi to wọn leti, ti wọn si lọ gbe e.
 
Awọn ọlọpaa lo ṣatọna bi wọn ṣe lọ ṣayẹwo fun ọmọ naa, ti wọn si n tọju rẹ lọwọ.
 
Ọpalọla ni lẹyin ti iwadii ba tubọ pari, awọn yoo f'oju Adewale ba ile-ẹjọ lati gba idajọ to tọ si i.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI