Mo ti n kọ awọn ọmọkunrin mi lati maa ba awọn ọmọbinrin laṣepọ bi wọn ba dagba - Ṣeyi Awolọwọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, August 24, 2023

Mo ti n kọ awọn ọmọkunrin mi lati maa ba awọn ọmọbinrin laṣepọ bi wọn ba dagba - Ṣeyi Awolọwọ


Ọkan lara awọn gbajumọ lori eto Ẹlẹgbọn Agba Naija, iyẹn Big Brother Naija, Ọgbẹni Ṣeyi Awolọwọ ti sọ ọ sita lori ikanni ayelujara wi pe oun ti bẹrẹ sii kọ awọn ọmọkunrin oun lati mọ bi wọn ṣe n ba awọn ọmọbinrin ọmọlọmọ laṣepọ bi wọn ba dagba.
 
Laipẹ yii ni Ṣeyi Awolọwọ sọrọ naa jade, too si tun sọ pe idi rẹ gan-an niyẹn loun fi n bimọ ọkunrin jọ, ki wọn le maa bọ pata awọnọmọbinrin.
 
Awọlọwọ sọrọ yii lakoko to n ba awọn akẹgbẹ rẹ Whitemoney ati Soma sọrọ, ọrọ naa lo si tan kaakiri ori ikanni ayelujara, to mu k'awọn ololurẹ rẹ, paapaa awọn to gbọ sii maa sọ oriṣiriṣi.
 
Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe oun ti ṣi apo ifowopamọ si f'awọn ọmọ oun, eyi ti wọn le maa na f'awọn ọmọbinrin ti wọn ba fẹẹ ba laṣepọ, ti ko si nii ni wọn lara.
 
Ninu ọrọ rẹ, o ni, “Mo n bimọ ọkunrin jọ, ki wọn le maa gbo awọn ọmọbinrin ọmọlọmọ nigbokugbo.

“Mo ti ṣi apo ifowopamọsi fun ọmọkunrin mi lati maa lo lati fi ba awọn ọmọbinrin olobinrin laṣepọ.

“Maa fun un ni kọkọrọ mọto mi ati kọkọrọ yara alejo nibi to ti maa lọ ba wọn laṣepọ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI