Njẹ ẹ ranti awọn to padanu dukia wọn lakoko omiyale ni Kwara lọdun 2022? Ijọba tun ti dide iranwọ miran fun wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, August 24, 2023

Njẹ ẹ ranti awọn to padanu dukia wọn lakoko omiyale ni Kwara lọdun 2022? Ijọba tun ti dide iranwọ miran fun wọn


Bi wọn ba n ṣapejuwe ijọba mẹkunnu lorileede Naijiria lakoko ti a wa yii, ko si ijọba meji to le ṣaaju to kọja ijọba ipinlẹ Kwara, nitori pe gbogbo nnkan to le mu irọrun ati igbayegbadun ba araalu ni wọn n ṣe.
 
L'opin ọsẹ to kọja yii ni ijọba ipinlẹ naa tun gbe eto iranwọ miran kalẹ f'awọn to padanu dukia wọn lakoko omiyale-agbaraya-ṣọọbu to ṣẹlẹ lọdun 2022.
 
Eto iranwọ naa ni ijọba pe ni Special National Economic Livelihood Emergency Intervention (SNELEI), nibi ti awọn eeyan tii bẹrẹ sii gba awọn nnkan iranwọ loriṣiriṣi niluu Ilọrin.
 
Nibi ifilọlẹ eto ọhun ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tun ti ṣeleri pe gbogbo ohun to ba yẹ ni iṣakoso oun yoo maa ṣe lati rii pe awọn araalu jẹ mudunmudun iṣejọba awaarawa.

Igbakeji gomina, Ọgbẹni Kayọde Alabi, nigba to n gba ẹnu ọga rẹ sọrọ, o ni ijọba wọn n ṣe ohun to yẹ lati rii pe wọn ni ajọṣepọ to dan mọnran pẹlu awọn eeyan, ileeṣẹ ati ajọ fun idagbasoke ati ilọsiwaju ipinlẹ naa.

Nibẹ lo ti gbe oṣuba kare fun ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri lorileede Naijiria, National Emergency Management Agency (NEMA) ati ti ipinlẹ, State Emergency Management Agency (SEMA) fun igbesẹ ti wọn gbe lati mọ iye awọn ti ajalu naa kan, lai figbakan bo ọkan ninu, ati bi wọn ṣe mu awọn nnkan idẹrun wa f'awọn eeyan naa.

Gomina ni agbara omiyale naa ṣọṣẹ to pọ to si ba dukia, oko ati iree oko to le ni ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu jẹ.

Ọgbẹni Ephriam Tony, to ṣoju alakoso agba fun aọ NEMA sọ pe eto iranwọ naa ni wọn gbe kalẹ lati mu ki idagbasoke tubọ de ba eto ọrọ aje ati igbayegbadun araalu, paapaa awọn to ku diẹ kaato fun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI