O ma ṣe o! Wọn yinbọn pa maugbalẹgbẹ Sẹnetọ Yayi danu l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, August 6, 2023

O ma ṣe o! Wọn yinbọn pa maugbalẹgbẹ Sẹnetọ Yayi danu l'Ekoo


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii lọrọ iku ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun Ogun West, Sẹnetọ Solomon Ọlamilekan Adeọla t'ọpọ awọn eeyan mọ si Yayi, Adeniyi Sanni ṣi n jẹ fun ọpọ awọn to gbọ.
 
Aarọ ọjọ Abamẹta tii ṣe Satide to kọja yii la gbọ pe awọn agbebọn kan tẹnikẹni ko tii mọ yinbọn pa Sanni sagbegbe Oṣhodi, ipinlẹ Ekoo.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni awọn kan ti wọn wọ aṣọ ọlọpaa ni wọn sa Sanni duro lagbegbe Berger, ti wọn si n beere awọn iwe mọto rẹ, eyi ti ko si ninu mọto ọhun lasiko naa.

Wọn ni loju ẹsẹ lo ti pe iyawo rẹ lori foonu wi pe ko ba oun ya awọn iwe ọkọ naa, ko si fi ranṣẹ sori foonu oun pẹlu ikanni wasaapu.

Loju ẹsẹ la gbọ pe obinrin naa fi awọn iwe naa ranṣẹ, ti wọn si ni Sanni fi han awọn to da a duro.

Lẹyin eyi ni wọn sọ pe obinrin naa tun pe ọkọ rẹ lati mọ ohun to n ṣẹlẹ, to si sọ fun un wi pe awọn ṣi n yanju rẹ lọwọ.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ Sẹnetọ Adeọla Yayi, Kayọde Ọdunaro fi sita lo ti jẹ ko di mimọ pe iyawo Sanni tun pe ọkọ rẹ lori foonu, ṣugbọn ti foonu rẹ ko lọ mọ.

Eyi lo jẹ ko maa fura wi pe boya nnkan ti ṣẹlẹ si ọkọ rẹ, to si n ranṣẹ pe awọn eeyan lati fi to wọn leti.

Lẹyin ọpọ wakati la gbọ pe ẹnikan pe foonu iyawo Sanni, to si fi to o leti wi pe awọn ba oku ọkọ rẹ ninu mọto lẹgbẹ opopona lagbegbe ibudokọ Toyota to wa ni Oṣhodi.
 
Ọdunaro sọ pe ile ni Sanni n lọ lagbegbe Iṣhẹri, ko to di pe awọn kan da a duro ni Berger lati maa beere fun iwe mọto rẹ, to si ni iyawo rẹ fi ranṣẹ sii
 
O wa fi ye wa pe ibanujẹ ni iroyin naa jẹ fun Sẹnetọ Yayi, ẹni to jẹ ọkan lara awọn to n ṣagbeyẹwo awọn minisita ti aarẹ Tinubu fi orukọ wọn ranṣẹ sile igbimọ aṣofin agba lorileede yii
 
Bẹẹ lo fi kun ọrọ rẹ pe awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lati mọ awọn to lọwọ si iku Sanni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI