Oku iya arugbo ti wọn fẹẹ sin poora ni mọṣuari l'Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, August 6, 2023

Oku iya arugbo ti wọn fẹẹ sin poora ni mọṣuari l'Ondo


Niṣe lọrọ di gbọnmisi-omioto lọjọ Ẹti tii ṣe Furaide to kọja yii nigba ti wọn sọ pe awọn mọlẹbi kan ko ri oku eeyan wọn ti wọn gbe pamọ si mọṣuari, eyi ti wọn fẹẹ pada lọ sin.
 
Iya agba, ẹni ọdun mẹtalelọgọta kan, Arabinrin Ọlajumọkẹ Julianah Ogunsuyi la gbọ pe o dagbere faye ni nnkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin, ti wọn si l'awọn mọlẹbi gbe oku rẹ lọ si mọṣuari, ọsibitu University of Medical Sciences (UNIMED) Teaching Hospital to wa niluu Osi, ijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, ipinlẹ Ondo.

Gbogbo owo ti wọn lo yẹ ki wọn san la gbọ pe awọn mọlẹbi ko silẹ, ti wọn si lọ ṣe ipalẹmọ bi wọn yoo ṣe sinku naa lọjọ Abamẹta tii ṣe Satide to kọja yii.

A gbọ pe lẹyin ipalẹmọ l'awọn mọlẹbi fẹnuko lati sinku naa lọjọ Satide, ọjọ karun-un, oṣu kẹjọ ti a wa ninu ẹ yii. Bi wọn ṣe de mọṣuari naa ni wọn sọ pe ọrọ di 'wo mi n wo ẹ', nigba ti wọn lawọn to wa ni mọṣuari sọ pe awọn ko ri oku ti wọn gbe wa.
 
Gbogbo inu mọṣuari naa ni wọn yẹ wo, ṣugbọn ti wọn ko ri nnkan to jọ oku Arabinrin Ogunsuyi nibẹ, eyi lo jẹ ki ariwo bẹ silẹ nibẹ, tọrọ si di faa ka ja.

Lara awọn mọlẹbi to ba awọn akọroyin sọrọ jẹ ko di mimọ pe ibi ti oku naa ba wọlẹ si, wọn gbọdọ gbe e jade fun wọn, nitori pe awọn ko nii gba.
 
Ọlọpaa kan to mọ nipa iṣẹlẹ yii ṣalaye pe awọn ti pe awọn alaṣẹ ọsibitu naa ati awọn to n mojuto mọṣuari ọhun fun ifọrọwanilẹnuwo lati mọ bi oku naa ṣe poora, to si ni iwadii ti n lọ lọwọ.
 
Gbogbo akitiyan lati ba agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Funmilayọ Ọdunlami-Omisanya sọrọ lati f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ lo ja si pabo titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI