O pari! Wọn ji iyawo pasitọ ijọ Ridiimu gbe ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, August 19, 2023

O pari! Wọn ji iyawo pasitọ ijọ Ridiimu gbe ni Kwara


Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii tan la ko ti i gbọ pe boya wọn ti fi iyawo ọkan lara awọn pasitọ ijọ Ridiimu to jẹ ti Baba Adeboye, iyẹn
Redeemed Christian Church of God, RCCG, ti wọn jigbe silẹ, sibẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ṣi n sọ pe ko tii sẹni to wa fi ọrọ ijinigbe to awọn leti.
 
Nnkan bi aago mẹsan alẹ Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ yii la gbọ pe awọn ajinigbe kan yabo ile Pasitọ naa, Johnson Ajiboye, to wa labule Elerinjare, nitosi Idofian, ijọba ibilẹ Ifẹlodun, ipinlẹ Kwara, pẹlu ibọn.
 
Wọn ni bi wọn ṣe de agbegbe naa ni wọn ti dabọn bolẹ ko to di pe wọn wọnu ile pasitọ naa, ti wọn si ji iyawo rẹ, Arabinrin Bọla Ajiboye gbe salọ.
 
Iroyin tẹ wa lọwọ sọ pe ọkan lara awọn ọmọ wọn to wa ninu ile lasiko naa juba ehoro lati sa asala fun ẹmi ara rẹ lọjọ naa, ki wọn too ji obinrin naa gbe.
 
A gbọ pe pasitọ naa gbọ iro ibọn, ṣugbọn ti ko mọ pe ile oun ni wọn ti yinbọn naa, wọn nigba ti awọn ajinigbe naa lọ tan, lo to ṣẹṣẹ mọ pe ara oun ni iso ti n run.
 
SP Ọkasanmi Ajayi, to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ naa, nigba to n sọrọ ṣalaye pe awọn ko tii gbọ ki ẹnikankan wa fi to awọn leti, o loo digba t'awọn ba gbọ ki igbesẹ too bẹrẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI