Ọmọ ọgbọn ọdun to lu Saheed Balogun ni jibiti miliọnu kan naira dero ile-ẹjọ l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, August 12, 2023

Ọmọ ọgbọn ọdun to lu Saheed Balogun ni jibiti miliọnu kan naira dero ile-ẹjọ l'Ekoo


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekoo ti f'oju Fabian Udenyi, ẹni ọgbọn ọdun ba ile-ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Ejigbe, ipinlẹ naa lori ẹsun jibiti, ẹtanjẹ ati ilọnilọwọgba.
 
Ọjọ Ẹti tii ṣe Furaide to kọja yii ni ileeṣẹ ọlọpaa foju Fabian ba ile-ẹjọ, miliọnu kan le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan naira, N1.1m ni wọn sọ pe ọmọkunrin naa lu jibiti ẹ.
 
Gẹgẹ bi ASP Benedict Aigbokhan to jẹ agbefọba ṣe ṣalaye niwaju Onidajọ I. A Ariyọ, o ni inu oṣu keji, ọdun ti a wa yii ni Fabian gba owo naa lojule kẹwaa, adugbo Adeṣina, Idimu nipinlẹ Ekoo lọwọ Saheed Balogun.

Wọn ni niṣe lo sọ fun Balogun pe oun fẹ ba a f'owo naa dokoowo ni, ṣugbọn to bẹrẹ sii na owo ọhun ninakuna funra rẹ, to si n jaye familete-ki-n-tutọ.
 
Aigbokhan ni latigba ti Fabian ti gba owo naa, lo ti n foni-da oni, ọla da ọla fun Balogun, koda, to tun n leri wi pe owo naa ba nnkan miran lọ.
 
Eyi ni wọn lo jẹ ki Balogun lọ fẹjọ sun awọn ọlọpaa, ko to di pe wọn rọwọ to o, ti wọn si sọ pe ẹsun naa tako iwe ofin ọdaran ti abala 287(1) ati 314, tipinlẹ Ekoo lọdun 2015.
 
Bo tilẹ jẹ pe Fabian loun ko jẹbi pẹlu alaye, ṣugbọn Onidajọ Ariyọ sọ pe ko tii ni ọrọ kankan lẹnu, ati pe oun yoo ṣi foju aanu wo o lati gba beeli rẹ pẹlu ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira ati oniduro meji ọtọọtọ ti wọn n san owo ori wọno deedee s'apo ijọba ipinlẹ naa.

Onidajọ Ariyọ ti wa a sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹrin,oṣu kẹsan, ọdun 2023.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI