Taye pa awọn ọmọ aburo meji l'Abẹokuta, o ni ogo oun lo n lo fi ṣaye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, August 12, 2023

Taye pa awọn ọmọ aburo meji l'Abẹokuta, o ni ogo oun lo n lo fi ṣaye


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii lọrọ baale ile kan, Taye Agbaje ṣi n jẹ f'awọn araalu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, paapaa awọn to gbọ, lori bo ṣe pa awọn ọmọ aburo rẹ meji danu, to si tun n sọ pe oun ṣẹṣẹ bẹrẹ ni.

Ọkunrin naa la gbọ pe o gbe ọkada lọ sile aburo rẹ to wa lagbegbe Kemta Abata, ijọba ibilẹ Guusu Abẹokuta lọjọ Abamẹta tii ṣe Satide, ọsẹ to kọja, iyẹn ọjọ karun-un, oṣu kẹjọ, ọdun 2023.

Wọn ni bi Taye ṣe debẹ, lo pe awọn ọmọ naa, to si fi ọkada ko wọn lọ sinu igbo kijikiji kan to wa lagbegbe Mile 6, Ajebọ, iyẹn niluu Abẹokuta.

Bo ṣe debẹ, ni wọn sọ pe o ya ada yọ, to si fi ge awọn ọmọ yii ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun meje si mẹsan lọ.
 
Promise ati Testimony lorukọ awọn ọmọ naa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ. Asiko ti wọn ni Idowu Agbaje to jẹ baba awọn ọmọ naa ko si nile ni Taye raaye lọ ṣiṣẹ buruku naa.
 
Igba ti wọn sọ pe Idowu de ile ni irọlẹ ọjọ naa, lo beere awọn ọmọ rẹ, t'awọn eeyan si l'awọn ko ri wọn. Eyi lo mu ko bẹrẹ sii wa wọn kaakiri.
 
Wọn ni Idowu pe Taye lori foonu lati beere awọon ọmọ rẹ, to si loun ko ri wọn. Lati ma jẹ ki aṣiri tu, wọn ni Taye gbera lọ sile aburo rẹ yii, o pẹlu bẹrẹ sii wa awọn ọmọ naa.
 
Lara awọn ara adugbo  to kofiri Taye lọsan ọjọ naa ni wọn koju rẹ pe oun lo ko wọn jade kuro nile. Igba ti ko fẹẹ jẹwọ ni wọn mu u lọ teṣan ọlọpaa Kemta lati fi to awọn ọlọpaa leti.
 
Lẹyin o rẹyin, Taye pada jẹwọ wi pe lootọ loun ko awọn ọmọ naa,ṣugbọn to loun ti lọ pa wọn danu sinu igbo kan lagbegbe Mile 6.
 
Aarọ ọjọ keji to jẹ ọjọ Aiku, Sannde to kọja lo mu awọn ọlọpaa lọ sibi to pa awọn ọmọ ọhun danu si. Eyi lo jẹ ki ariwo sọ kaakiri agbegbe naa.
 
Ẹsun ti wọn ni Taye fi kan aburo rẹ ni pe, o sọ pe iyawo aburo ti gba ogo oun fun aburo oun, bẹẹ lo sọ pe oun kan n ṣiṣẹ lasan lai ni akojọ ni.
 
Ọmọlọla Odutọla to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa nigba to n sọrọ ṣalaye pe iwadii ti bẹrẹ lẹkunrẹrẹ, to si ni ọdaju paraku ni Taye lori iwa buruku naa.

O ni Taye ko ri ọrọ gidi kan sọ lẹnu, bẹẹ ni ko ni imọlara wi pe nnkan toun ṣe ko dara rara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI