Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe gbogbo eto ni yoo bẹrẹ laipẹ lati bẹrẹ sii sọ gbogbo awọn ọkọ ijọba ipinlẹ naa di eyi ti yoo maa lo ina ẹlẹntiriki, dipo epo bẹntiroolu ti wọn n lo tẹlẹ, ti yoo si din inawo rẹpẹtẹ ku.
AbdulRazaq lo sọ eyi di mimọ l'Ọjọbọ tii ṣe Tọside to kọja yii, lakoko to n gba ikọ awọn onimọ-ẹrọ lati fasiti ipinlẹ naa lalejo, lori aṣeyọri ti wọn ṣe lati ṣe ọkọ bọọsi to n lo ina ẹlẹntiriki.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, awọn onimọ-ẹrọ naa la gbọ pe wọn ṣiṣẹ takuntakun lati yi awọn bọọsi kan pada kuro ni eyi to n lo epo bẹntiroolu si eyi ti yoo maa bẹrẹ sii lo ina mọnamọna, iyẹn ẹlẹntiriki, lati din owo epo ku.
Awọn mọto ọhun ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq sọ pe wọn n ṣiṣẹ daadaa lai labuku, ati pe iwuri nla lo jẹ wi pe Kwara naa pẹlu awọn ipinlẹ to kọkọ ṣe iru nnkan bayii.
O ni bo ṣe jẹ iwuri, naa lo tun jẹ idunnu wi pe ipinlẹ Kwara naa yo darapọ pẹlu awọn orileede nla-nla lagbayye ti yoo bẹrẹ sii lo ina ẹlẹntiriki fun ọkọ, ati pe asiko ti wọn nilo awọn ọkọ naa ju ree, iyẹn lasiko ọwọngogo epo to wa nita.
Nibẹ lo ti wa gbe oṣuba kare fun igbimọ awọn onimọ-ẹrọ naa ti Omimọ-ẹrọ AbdulAzeez Akande jẹ olori wọn, iyẹn ni ẹka Technical Unit Centre for Sustainable Energy and Chief Technologist, ẹka ikẹkọọ Electrical and Computer Engineering.
Bakan naa lo tun gbe oṣuba nla fun giwa fasiti naa, Ọjọgbọn Shaykh Lukman Jimoh, to lewaju ikọ ọhun wa si ile-igbe ijọba to wa niluu Ilọrin.
O wa fi da wọn loju pe oun yoo tubọ sa ipa oun lati ṣagbatẹru gbogbo ohun ti yoo ba mu idẹrun ba igbayegbadun araalu.
Bẹẹ lo ni oun ti paṣẹ fun awọn igbimọ kan lati bẹrẹ sii sọ pupọ awọn mọto ijọba ti eyi ti yoo maa lo ina ẹlẹntiriki, ki wọn si ko wọn lọ s'awọn ile-ẹkọ giga fun anfaani awọn akẹkọọ to wa nibẹ.
No comments:
Post a Comment