Gomina AbdulRazaq ba AbdulBaqi, Onilu yọ fun ti jijawe olubori gẹgẹ ọmọ igbimọ akoso ẹgbẹ NIPR - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, August 27, 2023

Gomina AbdulRazaq ba AbdulBaqi, Onilu yọ fun ti jijawe olubori gẹgẹ ọmọ igbimọ akoso ẹgbẹ NIPR


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ki Ọmọwe Saudat Salah AbdulBaqi ati ọkan lara awọn alẹnulọrọ f'ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congess, APC, Alaaji Lanre Issa Onilu ku oriire nla, gẹgẹ bi wọn ṣe jawe olubori ninu eto idibo to gbe wọn wọle gẹgẹ bi ọmọ alakoso f'ẹgbẹ  Nigerian Institute of Public Relations (NIPR).

Ọjọ Ẹti tii ṣe Furaidee to kọja yii ni wọn dibo yan Ọmọwe AbdulBaqi, gbajugbaja olukọ ni ọkan lara awọn ile-ẹkọ fasiti lorileede Naijiria gẹgẹ bi ọmọ igbimọ, ti wọn si kede Onilu gẹgẹ bi ọkan lara awọn aṣoju ijọba apapọ ninu igbimọ naa.

Bẹ o ba gbagbe, ni nnkan bi ọjọ meloo sẹyin ni Gomina AbudulRazaq dide ipolongo fun Ọmọwe AbdulBaqi, to si rọ awọn ikọ ti yoo dibo lati dibo fun obinrin naa to n gbe ipinlẹ Kwara larugẹ ni gbogbo igba, ati pe oun nigbagbọ ninu ẹ.
 
Ọmọwe  AbdulBaqi jẹ adari ẹka ikẹkọọ Mass Communication ni fasiti ilu Ilọrin tẹlẹ, bẹẹ naa lo tun jẹ alaga f'ẹgbẹ NIPR naa nipinlẹ Kwara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI