AbdulRazaq di baba isalẹ f'ẹgbẹ awọn akọwe-agba to ti fẹyinti (Fọto) - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 14, 2023

AbdulRazaq di baba isalẹ f'ẹgbẹ awọn akọwe-agba to ti fẹyinti (Fọto)


Itan tuntun lo tun balẹ fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara nigba ti awọn akọwe agba ti wọn ti fẹyinti panupọ lati sọ ọ di baba isalẹ, iyẹn Grand Patron ẹgbẹ wọn. 
 
Ẹgbẹ naa, Association of Retired States' Permanent Secretaries of Nigeria (ARSPSON), ẹka ti ipinlẹ Kwara l'Ọjọru tii ṣe Wẹsidee, ọsẹ yii ni awọn oloye ẹgbẹ naa.

Lakoko ti wọn n gbe iwe ẹri gẹgẹ bii baba isalẹ fun Gomina AbdulRazaq, alaga ẹgbẹ naa, Ọmọọba Ayọ Fagbemi sọ pe ọrẹ awọn ni, to si di dandan k'awọn fi ipo naa da a lọla, nitori ifẹ to fi n han si wọn ni gbogbo igba.
 
 
 
Laipẹ yii ni Gomina AbdulRazaq fi awọn meji ti wọn ni ipenija ara ṣe akọwe agba n'ipinlẹ naa, to si mu k'awọn eeyan maa sọ oriṣiriṣi, koda ti ọrọ naa di ariyanjiyan.

Awọn agbaagba ẹgbẹ naa wa gboriyin fun gomina lori bo ṣe n fun wọn ni ẹtọ wọn lasiko yii
 
Lara awọn to wa nibẹ ni akọwe ijọba ipinlẹ naa tẹlẹ, Alaaji Salman Ibrahim; akọwe agba ipinlẹ naa tẹlẹ, Sẹnetọ Mohammed Ahmẹd; olori awọn oṣiṣẹ ijọba tẹlẹ, Alaaji Mudi Gold.

 
 
Awọn miran ni: Igbakeji alaga, Hajiya Kikẹlọmọ Amọsa; Alaga Civil Service Commission, Hajiya Habibat Yusuf; Alagba David Adeṣina, ati Hajiya Mariam Garba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI