Ọna ti ileeṣẹ Adron Homes n gba ṣe iranwọ f'awọn araalu nipa ile gbigbe pẹlu idẹrun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 12, 2023

Ọna ti ileeṣẹ Adron Homes n gba ṣe iranwọ f'awọn araalu nipa ile gbigbe pẹlu idẹrun


Kii ṣe tuntun mọ pe lara awọn nnkan to jẹ gbajugbaja ileeṣẹ to n ṣowo ile gbigbe, ilẹ ati dukia, iyẹn Adron Homes and Properties Limited logun ni bi araalu yoo ṣe ni ibi ti wọn n fi ori wọn pamọ si lai laagun jinna.

Eto yii, to tun wa lara afojusun ijọba Naijiria labẹ iṣakoso Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu.

Bi eto ọrọ aje orileede yii ṣe n fi ojoojumọ le koko fun araalu, paapaa lasiko ọwọngogo epo rọbii, to si mu ko jẹ iṣoro fawọn eeyan lati ronu ọna ti wọn le gba di onile lori, lo fa a ti ileeṣẹ Adron Homes fi pinnu lati mu oriṣiriṣi ọna idẹrun ti yoo sọ araalu di onile lori.

Ẹgbẹlẹgbẹ ọmọ Naijiria ni wọn ṣi n la kaka lati ri ibi ti wọn yoo fi ori ara wọn pamọ si, depodepo wi pe wọn yoo di onile lori, ti iwadii si sọ pe ida ọgbọn ni awọn eeyan to n la kaka yii.

A gbọ pe lara awọn ipenija to n koju ọrọ ile gbigbe lorileede Naijiria lasiko yii ni aisi awọn ile gbigbe to kun oju oṣuwọn to lati fi han. Ko si nnkan meji to si fa a, to kọja wi pe awọn ti wọn n pe ara wọn ni oniṣowo ile ati ilẹ kọ lati ṣe ojuṣe wọn nipa ṣiṣe iwadii to jinlẹ nipa ọna ti wọn le gba tan iṣoro araalu.

Ajọ to n ṣakoso ọrọ ile gbigbe lorileede Naijiria, iyẹn Nigeria Housing Policy ti sọ pe lati le pese ile gbigbe ti yoo to miliọnu mẹẹdogun, a nilo lati maa kọ ile gbigbe ti ko din ni miliọnu kan le ni igba (1.2million) ni ọdọọdun.

Bẹẹ si ree, Aarẹ Tinubu ti buwọ lu kikọ ile gbigbe ti ko din ni ẹgbẹrun kan si ipinlẹ bii Ṣokoto, Kẹbbi, Katsina, Zamfara, Kaduna, Niger ati Benue, to si ni eyi yoo mu adinku ba iṣoro ti awọn araalu n koju.

Lati le kin ijọba apapọ lẹyin, alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited, Aarẹ Adetọla EmmanuelKing ti wa sọ pe oun ṣetan lati dide iranwọ fun araalu nipa jija owo ilẹ ati dukia wọn wa silẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ninu atẹjade to tẹ wa lọwọ, wọn ni
"A ti wa nita bayii lati ja owo gbogbo awọn ile gbigbe wa silẹ kaakiri orileede Naijiria si ida aadọta, lati le jẹ ki ọmọ Naijiria di onile lori, lai nii ṣe pẹlu iye owo to n wọle fun wọn."

Anfaani yii la gbọ pe awọn alaṣẹ Adron gbe jade lati fi ran araalu lọwọ nipa idiyele, ẹbun ati sisan owo pẹlu irọrun.

Lara awọn agbegbe ti awọn eeyan le ti jẹ anfaani yii ni Ikorodu, Epe, Ede, Ibadan, kajola, Atan-Ọta, Ibeju Lekki, Badagry, Ijẹbu Ode, Shimawa, Abẹokuta, Ọṣun, Abuja ati Nasarawa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI