AbdulRazaq kẹdun iku Mubaarak ti wọn pa danu n'Ilọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, September 18, 2023

AbdulRazaq kẹdun iku Mubaarak ti wọn pa danu n'Ilọrin


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti kẹdun iku gendekunrin, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan Yusuf Mubaarak ti wọn ri oku rẹ ni ipo ti ko bojumu to, to si ti wa rọ awọn agbofinro lati tọpinpin iru iku to pa a.
 
Mubaarak to jẹ gbajugbaja akọroyin to jẹ ọmọ bibi iluu Ilọrin ni iroyin fi to wa leti pe o di awati l'Ọjọru tii ṣe Wẹsidee, ọsẹ to kọja yii, ṣugbọn ti wọn pada ri oku rẹ lagbegbe Unity
 
Opin ọsẹ to kọja ni wọn pada sinku Mubaarak, nibi t'awọn eeyan ti n gbera wọn ṣanlẹ
 
Gomina AbdulRazaq lakoko to n ba mọlẹbi oloogbe naa kẹdun kọminu lori bi wọn ṣe pa ọmọkunrin naa danu, to si ni iwa ọdaju l'awọn to ṣiṣẹ buruku naa hu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI