Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ba amugbalẹgbẹ agba pataki rẹ tẹlẹ lori ọrọ to nii ṣe pẹlu SDGs, Ọmọwe Jamila Bio Ibrahim yọ lori bi wọn ṣe yan an mọ awọn to kaju oṣuwọn lati di ipo minisita f'ọrọ awọn ọdọ lorileede Naijiria.
AbdulRazaq ni nnkan meji ni bi wọn ṣe yan Ọmọwe Jamila naa nii ṣe pẹlu, akọkọ ni pe irolagbara awọn ọdọ, to si ni ekeji ni aisi ẹyamẹya, iyẹn ni ti pe ati ọkunrin ati obinrin ninu ipinnu idagbasoke orileede yii.
O wa gboriyin fun Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu bo tun ṣe fẹẹ fi ipo miran to jẹ minisita da ipinlẹ naa lọla, ati pe lara awọn anfaani wi pe awọn araalu fara jin fun ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC) ni.
No comments:
Post a Comment