Alhaji Ayuba fi aṣọ ṣọja gba awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun silẹ lọwọ ẹṣọ aabo, lo ba loun ko mọ pe aṣiri maa pada tu sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 2, 2023

Alhaji Ayuba fi aṣọ ṣọja gba awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun silẹ lọwọ ẹṣọ aabo, lo ba loun ko mọ pe aṣiri maa pada tu sita


'Okete gbagbe ibosi, o gbe 'igba alatẹ, o kawọ mọri' lọrọ gendekunrin ti ẹ n wo oju rẹ yii, ẹni ti wọn lo n fi aṣọ ati kaadi idanimọ iṣẹ ologun lu awọn araalu ni jibiti, to si tun fi n ṣagbatẹru awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun 

Sanni Alhaji Ayuba ni wọn pe orukọ rẹ, ẹka ileeṣẹ ologun to wa lagbegbe Alamala niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun lo maa n sọ fawọn eeyan wi pe oun n ba ṣiṣẹ, to si jẹ pe ayederu pọmbele ni.

Ọsẹ to kọja yii ni omi pada dilẹ lẹyin asunṣujẹ rẹ, nigba ti ọwọ ẹṣọ aabo ipinlẹ Ogun ti a mọ si SO-SAFE CORPS tẹ ẹ, lẹyin to lọ fi ẹtanjẹ lu wọn ni jibiti, to si gba awọn afurasi ọdaran ti wọn silẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ ninu atẹjade ti agbẹnusọ fun ileeṣẹ So-Safe Coprs, Mọruf Yusuf fi sita ṣe ṣalaye, o ni awọn oṣiṣẹ wọn mu afurasi ọdaran ti wọn tun n ṣe ẹgbẹ okunkun.

Yusuf ni bi wọn ṣe mu awọn afurasi ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun naa lagbegbe Ọpako to wa ni Adigbẹ, ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode ni Ayuba ti lọ sibẹ, to si fi kaadi idanimọ rẹ gẹgẹ bi ologun han wọn.

Bo ṣe fi kaadi naa han wọn, to di pe wọn bẹrẹ sii fa ọrọ la gbọ pe awọn afurasi naa juba ehoro pẹlu ṣẹkẹṣẹkẹ mamugaari to wa lọwọ wọn.

Yusuf ninu ọrọ rẹ sọ pe "Bi wọn ṣe ko awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun naa, ti wọn si fẹẹ maa ko wọn lọ si ọfiisi, ni Ayuba ati awọn meji kan naa ti wọn farahan gẹgẹ bi ologun ori omi, iyẹn Naval Officers yọju si wọn.

"Niṣe ni awọn mẹtẹẹta yọ kaadi idanimọ sita, ti wọn si jẹ k'awọn eeyan naa salọ. Niṣe lọrọ naa dabi ẹfun, nitori pe ati Ayub ati awọn meji naa poora loju ẹsẹ.

"Iwadii kikun lo pada jẹ ki ọwọ pada tẹ Ayuba, ti wọn si ṣe iwadii rẹ nipa fifi ọrọ wa a lẹnu wo. Eyi gan-an lo jẹ ki aṣiri rẹ tu nitori pe ọrọ rẹ ko ba ara wọn mu."

Yusuf ni ọga awọn, Sọji Ganzallo koro oju si iwa yii, o si l'awọn eeyan yii n ba iṣẹ ologun jẹ, ati pe oun ko nii fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ awọn ayederu agbofinro kaakiri.

O ni Ayuba ti wa a pada jẹwọ daadaa wi pe o ti pẹ toun ti n fi aṣọ ati kaadi idanimọ naa lu jibiti lai mọ pe aṣiri maa pada tu sita.

Lara awọn nnkan to l'awọn gba lọwọ ẹ ni aṣọ ilewọ pelebe ti ologun, ayederu kaadi idanimọ ologun, ọbẹ kekere, foonu Itel kan, kaadi ATM mẹta ọtọọtọ, kaadi idanimọ ti WAEC, ṣẹkẹṣẹkẹ aja kan, ẹgba ọrun ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O wa fidi rẹ mulẹ pe awọn ti lọ fa a le awọn ọlọpaa CIID to wa ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ni Eleweran, Abẹokuta lọwọ lati tẹsiwaju iwadii wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI