Nibi ti eleyii ti fẹẹ fi ayederu ibọn jale lọwọ ti tẹ ẹ, ni wọn ba luu pa l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 2, 2023

Nibi ti eleyii ti fẹẹ fi ayederu ibọn jale lọwọ ti tẹ ẹ, ni wọn ba luu pa l'Ekoo


Niṣe lọrọ bẹyin yọ fun gendekunrin kan ti wọn fura si wi pe adigunjale ni, nigba tọwọ palaba rẹ segi, to si mu ki wọn luu titi to fi dagbere faye.

A gbọ pe afurasi adigunjale naa lo ja ilẹkun wọnu ile ẹnikan ti wọn pe orukọ rẹ ni Victor, pẹlu erongba lati digun jale.

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ekoo, Benjamin Hundryin nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ṣalaye pe ọsẹ to lọ lọhun niṣẹlẹ naa waye ladugbo Olugboṣo, Agege l'Ekoo.

O ni ayederu ibọn ni afurasi naa mu lọ digunjale lati fi dẹru ba awọn eeyan, ṣugbọn ti ọrọ pada yiwọ mọ ọn lọwọ.

Bo ṣe wọnu ile ni wọn sọ pe Victor to ni ile koju ija sii, ti wọn si lu ara wọn nilukulu. Nibi ti wọn ti n ja ni awọn ara agbegbe naa ti sare wọle, ti wọn si ọ ọ jade sita, ko to di pe gba ẹmi kuro lẹnu rẹ.

Hundeyin ni awọn ti gbe oku rẹ lọ si mọṣuari, bẹẹ ni Victor toun pẹlu rẹ jọ ja ti wa lọsibitu to ti n gba itọju lọwọ, ati pe iwadii ṣi n lọ lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI