Ayẹyẹ ifilọlẹ ni baale ile meji lọ ṣe ni ṣọọṣi Kerubu l'Ogun, ni wọn ba b'omi lọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 2, 2023

Ayẹyẹ ifilọlẹ ni baale ile meji lọ ṣe ni ṣọọṣi Kerubu l'Ogun, ni wọn ba b'omi lọ


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii lọrọ awọn baale ile meji kan ti wọn sọ pe wọn ba odo lọ sọrun aremabọ lagbegbe Onikoko to wa niluu Itori, ijọba ibilẹ Ewekoro n'ipinlẹ Ogun ṣi n jẹ fawọn eeyan, paapaa awọn ara agbegbe naa.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ṣọọṣi Kerubu ati Serafu kan to wa lagbegbe Onikoko, Itori ni wọn n ṣe ayẹyẹ ifilọlẹ, ti wọn si pe awọn alejo loriṣiriṣi.

Ilu Ekoo la gbọ pe awọn meji na ti lọ ba wọn ṣayẹyẹ ọhun n'ipinlẹ Ogun, lai mọ pe ọrọ yoo pads yiwọ.

Fẹmi Akinọla, ẹni ọdun mejilelọgbọn ati Tunde Falade, ẹni ọdun marundinlogoji la gbọ wọn jẹ Ọlọrun n'ipe.

Ọmọlọla Odutọla to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun nigba to n fidi iroyin ọhun mulẹ ṣalaye pe awọn meje ni wọn kuro l'Ekoo lati lọ ba wọn ṣayẹyẹ naa, iyẹn l'ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun 2023.

O ni bi wọn ṣe debẹ, ni wọn lọ wẹ lodo to wa nitosi ṣọọṣi naa, ti nnkan si yiwọ mọ wọn lọwọ. O l'awọn meji naa lo kuro ninu ṣọọṣi lati lọ wẹ.

Siwaju sii lo sọ pe nibi ti wọn ti n wẹ ni ọrọ ti yiwọ, to si jẹ pe awọn to wa nibẹ gbiyanju lati fa wọn yọ jade.

Loju ẹsẹ ni wọn ti sare gbe wọn digba-digba lọ si ọsibitu alabọde to wa niluu Itori, ṣugbọn to ṣeni laanu pe wọn ti ku.

Odutọla ni ẹni to ni ṣọọṣi naa, ti orukọ rẹ n jẹ Adebayọ Adeọṣun lo lọ fi to awọn ọlọpaa leti ni nnkan bi aago mẹfa aabọ irọlẹ 

Siwaju sii lo sọ pe nigba ti awọn ọlọpaa de agbegbe iṣẹlẹ naa, wọn ko ri ohunkohun to jọ bii ija tabi ohun to jọ bii ifurasi, ṣugbọn to sọ pe wọn ti gbe awọn oku naa wọ mọṣuari fun ayẹwo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI