Babalawo to fẹẹ ṣoogun owo fun mi lo sọ pe ki n mu nnkan ọmọkunrin baba mi wa - Ọmọ ogun ọdun to pa baba rẹ danu jẹwọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 2, 2023

Babalawo to fẹẹ ṣoogun owo fun mi lo sọ pe ki n mu nnkan ọmọkunrin baba mi wa - Ọmọ ogun ọdun to pa baba rẹ danu jẹwọ


Beeyan ba wa nibi ti gendekunrin, ọmọ ọgun nni, Ridwan tọwọ ẹṣọ aabo ipinlẹ Ogun ti a mọ si Ogun State Community, Social Orientation and Safety Corps, iyẹn So-Safe Corps tẹ laipẹ lori ẹsun wi pe o ṣa baba rẹ pa ti n ka boroboro, yoo mọ pe ọlẹ olojukokoro paraku ni, to si n wa owo ojiji ti ko ṣiṣẹ fun.
 
Ridwan ni iroyin rẹ tẹ wa lọwọ wi pe o ṣa baba rẹ pa pẹlu erongba lati fi ṣoogun owo l'abule Oshoku, ijọba ibilẹ Ariwa Ijẹbu, ipinlẹ Ogun.
 
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ fun ẹṣọ aabo So-Safe Corps naa, Mọruf Yusuf fi sita laipẹ yii, o ṣalaye pe asiko ti awọn oṣiṣẹ wọn n ṣiṣẹ kọja lọ ni nnkan bi aago mejila oru Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ yii ni wọn n gburo ariwo abami kan ninu ile kan, ti wọn si tọpinpin ariwo naa lọ.
 
Yusuf sọ pe bi wọn ṣe wọnu ile naa ni wọn wọnu ọkan lara awọn yara to wa nibẹ, to si jẹ kayeefi nla nigba ti wọn ba oku baba agbalagba kan ninu agbara ẹjẹ., ti wọn si lẹni to ṣiṣẹ buruku naa ti juba ehoro.
 
Loju ẹsẹ ni wọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lati mọ iru ẹni to ṣiṣẹ buruku naa. Si iyalẹnu, laaarin wakati mẹrinlelogun, ọwọ pada tẹ Ridwan ninu igbo to lọ sapamọ si.
 
Bọwọ ṣe tẹ ẹ, lo ti bẹrẹ sii ka boroboro wi pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ nitori pe iṣẹ eṣu. O ni babalawo kan to n jẹ Baba Kekere lo sọ pe koun lọ yọ nnkan ọmọkunrin, eyin mẹrin ati ikọfun baba oun, Ishau wa lati le ba oun fi ṣoogun owo.

Ridwan loun ko yọ ju awọn ẹya ara naa lọ, to si loun ti lọ ko o fun babalawo ọhun, eyi to ni iṣẹ ti bẹrẹ lẹkunrẹrẹ.
 
Bo tilẹ jẹ pe Ridwan kọ lati mu wọn lọ sibi ti babalawo naa wa, ṣugbọn o jẹ ki wọn mọ pe niṣe loun fi okun de baba oun ni ọwọ sẹyin ati ẹsẹ rẹ ko to di pe oun fi ada ge e si wẹwẹ.
 
Ọga agba pata fun ẹṣọ aabo naa, Sọji Ganzallo ti wa paṣẹ pe ki wọn lọ fa Ridwan le awọn ọlọpaa lọwọ lati tẹsiwaju iwadii lori ẹ, ati lati le gbe igbesẹ to tọ labẹ ofin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI