Mathew ṣa baba rẹ pa l'Ogun, o ni baba naa jẹ oun lowo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 1, 2023

Mathew ṣa baba rẹ pa l'Ogun, o ni baba naa jẹ oun lowo


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii l'awọn eeyan ṣi n gbe ọkunrin, ẹni ọdun mejidinlogoji kan, Mathew Ifeanyi ṣepe rabande-rabandẹ lori bi wọn ṣe loo ṣa baba to bii lọmọ pa sinu igbo.

Ojule kọkanla, adugbo Ibikunle,  Diamond Estate, to wa loju ọna Ọlọrunda, Ẹruobodo Ntabo, Ijoko, ijọba ibilẹ Ado-Odo, Ọta, ipinlẹ Ogun ni iṣẹlẹ ọhun ti waye l'ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
 
Gẹgẹ bi agbẹnusọ fun ileeṣẹ eleto aabo ipinlẹ Ogun ti a mọ si So-Safe Corps, Mọruf Yusuf ṣe ṣalaye,iwa ọdaju gba a ni Mathew hu naa, pẹlu bo ṣe ṣa baba rẹ, ẹni ọgọrun-un ọdun, Oloogbe Anthony Nnadike pa.
 
Yusuf sọ pe Mathew ko ri nnkan toun ṣe gẹgẹ bii pe o jẹbi iwa ọdaran naa, to si ni ọga awọn, Sọji Ganzallo ti paṣẹ pe ki wọn lọ fa a le awọn ọlọpaa lọwọ fun iwadii kikun.

Bakan naa lo fi kun un pe nigba ti wọn n fọrọ wa Mathew lẹnu wo, ohun to sọ ni pe oun ko owo ẹgbẹrun lọna aadọrin naira pamọ sọwọ baba oun lati inu oṣu keje, ọdun to kọja, to si ni baba naa ko k'owo ọhun silẹ foun titi di asiko toun fi pa a.

Mathew ni pẹlu ibinu loun fi ki ada mọlẹ, toun siṣa baba oun pa, nitori pe niṣe lo fẹẹ fi agba rẹ oun jẹ, toun ko si le gba a.

Yusuf ni awọn ara agbegbe naa lo ranṣẹ pe awọn oṣiṣẹ wọn lati wa daabo bo baba yii, to si lo ṣe awọn laanu pe baba naa dakẹ nigba to de ọsibitu, nitori ọpọ ẹjẹ to ti padanu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI