Ẹgbẹ awọn dokita ṣabẹwo si AbdulRazaq, wọn gboriyin fun iṣẹ takuntaun to n ṣe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 16, 2023

Ẹgbẹ awọn dokita ṣabẹwo si AbdulRazaq, wọn gboriyin fun iṣẹ takuntaun to n ṣe


Beeyan ba wa nibi ti ẹgbẹ awọn dokita n'ipinlẹ Kwara ti ṣabẹwo si Gomina AbdulRahman AbdulRazaq nile ijọba to wa niluu Ilọrin, ipinlẹ naa l'Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ yii, yoo mọ daju pe idunnu ṣubu lu ayọ wọn, ati pe lara awọn nnkan ti wọn n fẹ wa si imuṣẹ.

Ẹgbẹ awọn dokita labẹ aburada Nigerian Association of Resident Doctors (NARD) ni wọn lọ fi ẹmi imoore han si gomina wọn, ẹni to tun jẹ olori awọn gomina Naijiria lati dupẹ gidigidi lori ipa rere to n ko lẹka eto aabo.

Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni Gomina AbdulRazaq bu ọwọ lu sisan owo ijamba ati ajẹmọnu lẹnu iṣẹ (hazard and skipping allowance), pẹlu ida ọgọrun-un owo CONMESS.

Nibẹ ni awọn dokita naa tun ti gboriyin fun gomina yii pẹlu bo tun ṣe gba awọn dokita ati oṣiṣẹ eleto ilera sẹnu iṣẹ, lati di awọn aaye to ṣofo l'awọn ọsibitu kaakiri ipinlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI