Nitori ẹsun 'Yahoo-Yahoo', wọn ju Michael Odeh sẹwọn ọdun kan l'Abuja - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 16, 2023

Nitori ẹsun 'Yahoo-Yahoo', wọn ju Michael Odeh sẹwọn ọdun kan l'Abuja


Onidajọ O.A. Egwuatu ti ile-ẹjọ giga apapọ to wa lagbegbe Maitama niluu Abuja ti ju gendekunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ukoh Michael Odeh sẹwọn ọdun kan gbako pẹlu iṣẹ aṣekara lori ẹsun jibiti ori ikanni ayelujara ti a mọ 'Yahoo-Yahoo'.
 
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe Michael ko le ṣalaye ibi to ti ri owo ti ko din ni miliọnu mẹfa naira, eyi ti wọn ba ninu apo aṣuwọn ile ifowopamọ si rẹ, nigba ti ọwọ tẹ ẹ.
 
Gẹgẹ bi ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo kumọkumọ lorileede yii, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ẹka ti ilu Benue ṣe ṣalaye niwaju ile-ẹjọ l'ọjọ Ẹti tii ṣe Friade, ọsẹ yii, wọn ni olobo kan lo ta awọn wi pe awọn gendekunrin kan wa ti wọn n jaye familete-ki-n-tutọ.
 
Eyi ni wọn lo fa a ti wọn fi lọ ko wọn, ti Michael si wa lara awọn tọwọ tẹ.
 
Ninu ẹsun to nii ṣe pẹlu jibiti ti wọn fi kan an, wọn sọ pe inu apo aṣuwọn ti ile ifowopamọ ti FCMB pẹlu nọmba 4668442010 ni wọn ti ba miliọnu mẹfa naira naa, ti ko si le sọ ibi to ti ri owo naa, eyi to jẹ ki wọn nigbagbọ pe ojulowo ọmọ Yahoo gidi ni.
 
Ẹsun naa ni wọn lo tako iwe ofin gbigbe owo rin lai ni iwe aṣẹ, iyẹn Money Laundering ni abala ogun akọkọ, Section 20 (a), to si tun ni ijiya ninu ni abala ogun keji.
 
Michael niwaju ile-ẹjọ lo ti gba wi pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun, to si bẹbẹ fun idariji, ṣugbọn agbefọba M. Yusuf to fẹsun kan an rọ ile-ẹjọ lati dajọ fun un bo ti tọ ati bo ti yẹ, ko le kẹkọọ siwaju sii.
 
Onidajọ Egwuatu, wa a paṣẹ pe ki Michael lọ fi ẹwọn ọdun gbako gbara tabi ko san ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira gẹgẹ bi owo itanran, bẹẹ si ni yoo tun gbagbe ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira sọwọ ijọba Naijiria lati ọwọ EFCC.
 
Bakan naa ni ile-ẹjọ tun sọ pe ijọba ti gbẹsẹ le foonu Infinix 7 rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI