Gomina Adeleke gba awọn ọdọ lamọran lati dẹkun fifi ipa wa owo ti ko ba ofin mu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 23, 2023

Gomina Adeleke gba awọn ọdọ lamọran lati dẹkun fifi ipa wa owo ti ko ba ofin mu


Gomina Ademọla Adeleke ti ipinlẹ Ọṣun ti gba gbogbo awọn ọdọ lamọran lati dẹkun fifi ọna ẹburu wa owo pajawiri ti ko ba ofin mu
.
 
Adeleke lo sọrọ naa lasiko to n ba mọlẹbi gbajumọ olorin takasufee nni ti ogo rẹ ṣẹṣẹ n dide bọ, eyi to doloogbe laipẹ yii, Ilerioluwa Ọladimeji, ẹni ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Mohbad.
 
Ninu atẹjade ti kọmiṣanna fọrọ awọn ọdọ, Mọshood Ọlagunju gbe jade lorukọ ijọba lo ti sọ pe iku Mohbad jẹ eyi to ba ni ninu jẹ, to si pe fun iwadii ododo.
 
“Nipasẹ Gomina Ademọla Adeleke, mo fẹẹ gba gbogbo awọn ti ọrọ kan lamọran wi pe ki wọn ṣe ojuṣe wọn lati le jẹ ki iwadii ododo waye, leyi ti yoo jẹ ki ọwọ tẹ gbogbo awọn to lọwọ ninu iku Mohbad
 
“A dupẹ lọwọ ọga ọlọpaa orileede yii fun bo ṣe sọ pe ki iwadii bẹrẹ lai dawọ duro lati mọ iru iku to pa ọdọmọde olorin takasufee naa.
 
“Bakan naa la tun ba mọlẹbi oloogbe kẹdun fun bi wọn ṣe padanu ọmọ wọn. Ipinlẹ Ọṣun gbe oriyin fun awọn ọdọ ipinlẹ naa ti wọn darapọ mọ awọn ọmọ Naijiria lati ṣe iwọde ifẹhonuhan alalaafia.”
 
Siwaju sii lo tun sọ pe
“Ijọba ipinlẹ yii ti rọ awọn ọdọ lati tẹsiwaju nipa wi wa owo lọna to ba ofin mu, ki wọn si dẹkun fifi ọna ẹburu wa owo lọna aitọ, eyi to le da ẹmi wọn legbodo lojiji.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI