Ogun amudo ni Aminu fi kan ọmọ ọdun mejidinlogun, ni wọn ba ju sẹwọn ọdun marun-un ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 23, 2023

Ogun amudo ni Aminu fi kan ọmọ ọdun mejidinlogun, ni wọn ba ju sẹwọn ọdun marun-un ni Kwara


Ile-ẹjọ Majisireeti to wa nijọba ibilẹ Kaiama ti ju ọmọ ọdun mẹrinlelogun kan, Tashiu Aminu Lulu, sẹwọn ọdun marun-un gbako pẹlu iṣẹ aṣekara lori ẹsun wi pe o fi oogun abẹnugọngọ gba ọmọbinrin, ẹni ọdun mejidinlogun kan, to si ba a lajọṣepọ karakara.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ọmọbinrin naa lo lọ fi to ileeṣẹ eleto aabo ara ẹni laabo ilu ti a mọ si Sifu Difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara leti wi pe Aminu pe oun lori, o si fi oogun kan oun, ko to di pe o ba oun laṣepọ.
 
Ọjọru tii ṣe Wẹsidee, ọsẹ yii ni ọwọ tẹ Aminu, toun naa si jẹwọ pe otitọ ni, ati pe iṣẹ eṣu ni, idi ree to fi foju ba ile-ẹjọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ti wọn si juu sẹwọn ọdun marun-un gbako.
 
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ Sifu Difẹnsi nipinlẹ naa, Ayẹni Ọlasunkanmi fi sita, o ni nnkan bi aago mẹrin kọja iṣẹju marundinlọgbọn irọlẹ ni ọwọ tẹ Aminu lẹyin ti ọmọbinrin kan wa fi ẹjọ rẹ sun wọn.
 
Ayẹni sọ pe ilu Woro to wa ni ijọba ibilẹ Kaiama lọwọ ti tẹ ẹ.
 
O ni ọmọbinrin naa sọ pe Aminu pe oun lori foonu lati wa ba oun nile, to si loun gbera loju ẹsẹ lai mọ nnkan toun n ṣe mọ. Igba toun debẹ lo sọ pe Aminu ni koun bọ aṣọ, toun naa si ṣe bo ṣe sọ.

Siwaju sii lo ni lẹyin naa lo mu abẹfẹlẹ, to si ge irun ori oun, irun abiya oun ati irun abẹ oun, ko to di pe o gbe igba le oun lọwọ, to si n pogede, ko to di pe o ba oun lajọṣepọ.

Ọmọbinrin naa sọ pe latigba naa loun ti n la alakala, ti ọrọ ara oun ko si ye oun mọ, idi ree to fi lọ fi to awọn agbofinro leti, ti wọn si lọ mu.

Loju ẹsẹ ni ọga agba Sifu Difẹnsi nipinlẹ naa, J.G Mohammed paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ lẹkunrẹrẹ, to si ni Aminu pada jẹwọ pe lotitọ ni, ati pe iṣẹ eṣu ni.
 
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Majisireeti Abubakar Ahmed Boro paṣẹ pe ki Aminu lọ fi ẹwọn ọdun marun-un gbara ninu ẹsun ọdaran ti wọn fi kan an.

Ayẹni sọ pe iwe ofin ọdaran lilo oogun abẹnugọngọ, Criminal Charm (217), Criminal Assault and force (268) and gross indecency (285) to si ni ijiya ninu lawọn fi kan an.
 
Bẹẹ lo sọ pe ọgba ẹwọn Okekura to wa niluu Ilọrin ni yoo ti lo ẹwọn rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI