Idunnu n ṣubu lu ayọ awọn araalu ni Kwara lori ounjẹ idẹrun ti ijọba n pin lai lo oṣelu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, September 10, 2023

Idunnu n ṣubu lu ayọ awọn araalu ni Kwara lori ounjẹ idẹrun ti ijọba n pin lai lo oṣelu


Bo tilẹ jẹ pe latigba ti ijọba ipinlẹ Kwara ti bẹrẹ sii pin ounjẹ idẹrun ti a mọ si Palliatives fun awọn araalu ni wọn ko tii dawọ duro, sibẹ ọpẹ l'awọn eeyan da lori ọna ti ijọba gba lati pin awọn oúnjẹ naa.

Ijọba ibilẹ Ilọrin tii ṣe olu-ilu Ipinlẹ Kwara ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ṣiṣọ loju eegun ounjẹ naa, ko to di pe wọn gbe e kaakiri awọn ijọba ibilẹ yooku to wa nibẹ.

Lara awọn ijọba ibilẹ ti wọn ti jẹ anfaani ounjẹ idẹrun yii ni Kaiama, Ilọrin South, Ilọrin East, Patigi, Oke-Ero, Asa, Ọffa, Oyun ati Ekiti.

A gbọ pe awọn ti ijọba rii pe o ku diẹ kaato fun ni wọn n gbe awọn ounjẹ naa fun, lati le ni ipin ninu mudunmudun eto oṣelu awarawa.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI