Iṣẹ Bola-Bola ni Ibrahim fi n boju, ole lo n ja kaakiri - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 9, 2023

Iṣẹ Bola-Bola ni Ibrahim fi n boju, ole lo n ja kaakiri


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun labẹ ọga wọn, Abiọdun Alamutu ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ gendekunrin, ọmọ ọdun mọkanlelogun kan, Ibrahim Adamu to n fi iṣẹ awọn to n ṣa irin, iyẹn Bola-Bola kaakiri boju, ṣugbọn to jẹ pe ogbologbo adigunjale ni.
 
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọmọlọla Odutọla fi sita laipẹ yii, o ni awọn ọlọpaa ẹkun Itele Awori lo rọwọ to Ibrahim pẹlu awọn ẹrun to ji ko.
 
Odutọla ni Ibrahim ti kọkọ puro wi pe ori akitan loun ti lọ ṣa awọn ẹrun ti ba lọwọ oun, ṣugbọn to ni iwadii pada fidi rẹ mulẹ pe irọ nla to jinna si otitọ ni, nitori pe awọn ẹru naa ṣi tuntun fun lilo.
 
Ninu atẹjade naa ni Odutọla tun ti ṣalaye wi pe Ibrahim, ọmọ bibi ilu Adamawa naa ti jẹwọ pe awọn meji lawọn jọ n ṣiṣẹ, to si darukọ ẹnikeji naa gẹgẹ bii Azonto, ẹni to sọ pe o ti na papa bora nigba ti aṣiri fẹẹ tu.
 
Siwaju sii lo sọ pe asiko ti awọn eeyan ko ba si nile wọn, l'awọn eeyan yii maa n wọle lati ji awọn dukia inu wọn ko sinu apo ti wọn maa n gbe dani.
 
Lara awọn ẹru ti wọn gba lọwọ ẹ ni faanu loriṣiriṣi, waya ina loriṣiri, irin ati awọn nnkan miran.
 
Odutọla ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori Azonto to na papa bora, ati pe Ibrahim ti wa ni ẹka ileeṣẹ wọn to n ri sọrọ iwa ọdaran, iyẹn State Criminal Investigation Departments, bẹẹ lo fi kun ọrọ rẹ pe Ibrahin yoo foju ba ile-ẹjọ laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI