Kọmiṣanna fọrọ eto omi igbalode ṣabẹwo odo Aṣa, Sobi ati Agba fun akanṣe iṣẹ to n lọ lọwọ ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 9, 2023

Kọmiṣanna fọrọ eto omi igbalode ṣabẹwo odo Aṣa, Sobi ati Agba fun akanṣe iṣẹ to n lọ lọwọ ni Kwara


Kọmiṣanna fọrọ eto omi igbalode, Usman Yunusa Lade ti ṣabẹwo si awọn Odo Aṣa, Sobi ati Agba to wa niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara lati ṣabojuto awọn iṣẹ igbalode to n lọ lọwọ nibẹ, fun idẹrun araalu.
 
Bakan naa lo tun wo awọn ipenija ti awọn odo naa n koju, eyi to le fa ajakalẹ arun f'awọn to n jẹ anfaani odo naa, paapaa nipa mimu ati lilo.

Ni ti odo Aṣa, iyẹ Asa Dam Water Works, Kọmiṣanna naa ṣakiyesi pe akanṣe iṣẹ to n lọ lọwọ nibẹ ti fẹẹ pari, to si ni awọn agbaṣẹṣe to n ṣiṣẹ lọwọ nibẹ ti n yanju gbogbo iṣoro lati rii pe omi naa wa fun mimu ti ko lẹgbẹ.
 
Bakan naa lo tun ṣalaye lori odo Sobi ati Agba, to si ni bi awọn iṣẹ naa ba fi pari, araalu yoo tun bẹrẹ sii jẹ igbadun omi ẹrọ igbalode ti ko labula.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI