Gbogbo eto lo ti pari patapata bayii fun Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja keji lati wọ ilu Abẹokuta tii ṣe olu-ilu ipinlẹ Ogun, lati ba wọn ṣayẹyẹ ipo ọba tuntun niluu Orile-Ilawọ to wa n'ijọba ibilẹ Ọdẹda, ipinlẹ naa, eyi ti wọn fi Ọjọgbọn Oluṣẹgun Alexander Macgregor jẹ.
Yatọ si Ọọni Ifẹ, awọn ọba bii Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ; Ọṣilẹ Oke-Ọna Ẹgba, Ọba Adedapọ Adewale Tẹjuoṣo; Olowu tiluu Owu, Ọba Saka Matẹmilọla; Arujalẹ Ojima tiluu Okelusẹ niluu Ondo, Ọba Oloyede Adeyẹọba Akinghare keji naa yoo wa nibi eto ayẹyẹ ọhun, eyi to fẹẹ waye l'opin ọsẹ ti a wa yii.
Gbagede Helipad to wa lẹyin gbagede aṣa, iyẹn June 12 Cultural Centre, Kutọ ni eto ayẹyẹ ọhun yoo ti waye, bẹrẹ lati aago mẹwaa aarọ.
Nigba to n sọrọ nibi ipade awọn oniroyin to waye l'Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ana, Ọnarebu Ishaq Bada to jẹ alaga igbimọ ayẹyẹ naa, ṣalaye pe eto ọhun lo bẹrẹ ni pẹrẹu, lẹyin ti Ọba Macgregor ti lo aadọrun ọjọ ninu Ipebi.
Ọnarebu Bada sọ pe wọn yoo ṣe ayẹyẹ ita gbangba ọlọdọọdun, iyẹn carnival niluu Ilaw, eyi ti wọn yoo tun fun awọn araalu ni eto ayẹwo ọfẹ, ti wọn yoo si tun gba oogun ọfẹ.
Lonii tii ṣe ọjọ Ẹti, Furaide ni wọn yoo darapọ mọ awọn ẹlẹsin musulumi lati kirun Jimọ ni ago kan ọsan ni mọṣalaṣi agba ilu Orile-Ilawọ, Ansarul-Deen Central Mosque, Orile-Ilawo.
Bakan naa ni wọon yoo f'awọn oloye ati Baalẹ tuntun jẹ lawọn abule to wa labẹ Ilawọ, eto naa ti yoo waye ni Kabiyesi to wa niluu Ilawọ, Abẹokuta.
Ayẹyẹ naa ni yoo pari pẹlu isin idupẹ lọjọ Aiku tii se Sannde nile ijọsin St. Peter African Church, Ilawọ.
No comments:
Post a Comment