Nnkan de! Wọn yinbọn pa oloye ẹgbẹ oṣelu PDP l'Ọṣun niwaju ṣọọbu iyawo ẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 16, 2023

Nnkan de! Wọn yinbọn pa oloye ẹgbẹ oṣelu PDP l'Ọṣun niwaju ṣọọbu iyawo ẹ


Niṣe lọrọ di boolọ o yago lọna l'Ọjọbọ tii ṣe Tọside, ọsẹ yii nigba ti wọn sọ pe awọn agbebọn ti ẹnikẹni ko tii mọ titi di asiko ti a pari akojọpọ yii deedee yinbọn pa gbajugbaja agba oloṣelu ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), nipinlẹ Ọsun, Dele Agboọla.
 
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe Dele, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Agbo n jẹun lọwọ niwaju ṣọọbu iyawo rẹ niluu Agbo, ijọba ibilẹ Boripẹ, ipinlẹ Ọṣun ni, ko to di pe wọn yinbọn pa a.

Bi iro ibọn ṣe dun la gbọ pe awọn ara agbegbe naa sa asala fun ẹmi ara wọn, ti ko si s'ẹni to le da awọn to ṣiṣẹ buruku naa mọ titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.
 
Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn, nigba to n sọrọ ṣalaye pe Agbo, ẹni ọdun mejilelogoji naa n jẹun lọwọ niwaju ṣọọbu iyawo rẹ ni, ko to di pe wọn yinbọn fun un, ti awọn eeyan si sa asala fun ẹmi ara wọn.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ alaabo oju lalakan fi n ṣọri ti a mọ si Nigeria Security and Civil Defense Corps (NSCDC), Kẹhinde Adeleke, nigba to n f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ fi ye wa pe iwadii ti bẹrẹ lori awọn to ṣeku pa ọkunrin naa.
 
Adeleke ni awọn gbiyanju lati gba oku Agbo, ki wọn le lọ ṣayẹwo ti wọn n ṣe lati mọ iru iku to pa oku, iyẹn Autopsy, ṣugbọn to sọ pe awọn mẹlẹbi oloogbe ko gba, to si ni wọn ti sinku rẹ laago mẹjọ aabọ aarọ ọjọ Ẹti, Furaidee.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI