Ọwọ tẹ awọn mẹfa to dọgbọn si mita ijọba l'Ọṣun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 16, 2023

Ọwọ tẹ awọn mẹfa to dọgbọn si mita ijọba l'Ọṣun


Ileeṣẹ eleto aabo ara ẹni laabo ilu ti a mọ si Sifu Difẹnsi, ẹka t'ipinlẹ Ọṣun ti foju awọn mẹfa kan han fun gbogbo agbaye lori ẹsun wi pe wọn dọgbọn si ẹrọ to n ṣe onka ina mọnamọna ti a mọ si Prepaid Meter wọn.
 
Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ yii ni awọn Sifu Difẹnsi f'oju awọn eeyan naa han f'awọn akọroyin niluu Oṣogbo, nibi ti wọn ti jẹ ko di mimọ pe agbegbe Ọta-Ẹfun lọwọ ti tẹ wọn, lakoko ti awọn ati awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ mọnamọna ti Ibadan Electricity Distribution Company, IBEDC ti jọ ṣiṣẹ papọ.

Ọga agba fun ileeṣẹ Sifu Difẹnsi naa nipinlẹ Ọṣun, Sunday Agboọla nigba to n sọrọ ṣalaye pe awọn tọwọ tẹ naa ti jẹwọ pe otitọ ni, ati pe awọn ko mọ pe ẹṣẹ ni.

Agboọla wa rawọ ẹbẹ si awọn araalu lati ṣọra fun jiji dukia ijọba lo, ki wọn si maa daabo bo o lagbegbe wọn.

Bakan naa ni wọn tun foju ẹnikan ti wọn pe orukọ rẹ ni Sọdiq Oriọla Ayanlẹyẹ han f'awọn akọroyin lori ẹsun wi pe o lu jibiti miliọnu mẹtala naira.
 
A gbọ pe Sọdiq gba owo naa lọwọ ẹnikan to n jẹ Samel, pẹlu ẹtanjẹ wi pe oun yoo ba a ra ile pulọọti marun-un niluu Ikorodu, ipinlẹ Ekoo, ṣugbọn to jẹ pe niṣe lo na owo naa jẹ.
 
 
Ọga agba naa sọ pe Ayanlẹyẹ ti jẹwọ fun wọn wi pe lotitọ loun gba owo naa, ṣugbọn toun ko le ṣalaye boun ṣe na owo naa. Ẹsun to lo tako iwe ofin ọdaran orileede yii ni abala 419.
 
Bẹẹ lo fi da awọn eeyan loju pe yoo foju ba ile-ẹjọ lati gba idajọ to tọ sii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI