Ọwọ ọlọpaa tẹ awọn to pa amugbalẹgbẹ Yayi l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 19, 2023

Ọwọ ọlọpaa tẹ awọn to pa amugbalẹgbẹ Yayi l'Ekoo


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekoo ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn afurasi to pa amugbalẹgbẹ Sẹnetọ Ọlamilekan Adeọla ti ọpọ awọn eeyan mọ si Yayi, iyẹn Adeniyi Saani l'oṣu
 
Ọjọ Aje, Mọnde ana ni ọga ọlọpaa ipinlẹ Ekoo, Idowu Owohunwa f'idi rẹ mulẹ ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Ikẹja, to si ni olobo to tẹ awọn lọwọ lo jẹ k'awọn rọwọ to awọn mẹta ọhun.

Ọjọ karun-un, oṣu kẹjọ, ọdun yii ni wọn pa Sanni lagbegbe Ojodu Berger, lakoko to n lọ sile rẹ to wa ni Iṣhẹri l'Ekoo.

Owohunwa sọ pe ọpọ ẹmi l'awọn afurasi naa ti da legbodo, to si l'awọn ti gba ibọn mẹta ati awọn nnkan ija oloro miran lọwọ wọn.
 
Awọn mẹta naa ni Fred Azeez Okuno, ẹni ọdun mẹtalelogoji l'Ekoo; Lucky Idudu Michael, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn lati ipinlẹ Delta, ati Adedigba Ṣẹgun, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn lati Ibadan nipinlẹ Ọyọ.
 
Lara awọn nnkan ti wọn gba lọwọ wọn ni ibọn ilewọ tuntun pẹlu ọta ibọn mẹta; ibọn ẹlẹnu kan pẹlu ọta ibọn mẹta; ibọn agbelẹrọ kan pẹlu ọta ibọn mẹfa; expended cartridges mẹfa; apọ ologun to kun fun aṣọ ati awọn ẹru ologun, to fi mọ akọ ayọkẹlẹ Honda CRV pupa.




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI