AbdulRazaq bá ọ̀gá ológun Nàìjíríà ṣèpàdé lórí ètò ààbò - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, October 4, 2023

AbdulRazaq bá ọ̀gá ológun Nàìjíríà ṣèpàdé lórí ètò ààbò


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ti ba ọga agba ileeṣẹ ologun orile-ede Naijiria, Jẹnẹra Adebayọ Abdulrahman Babalọla lalejo, bẹẹ ni wọn jọ ṣe ipade lori ọrọ eto aabo.

Ile ijọba to wa niluu Ilọrin, ipinlẹ naa la gbọ pe Ọgagun Babalọla ti lọ ba gomina lori ajọsọ nipa eto aabo.


Bi ẹ ko ba gbagbe, ileeṣẹ ologun nko ipa to jọju gidigidi lori eto aabo nipinlẹ Kwara lasiko yii.

Ọgagun Babalọla ti wa jẹ ko di nimọ pe awọn ko nii da ọwọ pipese aabo fun awọn araalu duro, paapaa n'ipinlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI