Ọọni Ifẹ f'ọkan araalu balẹ lori iṣoro to n dojukọ Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, October 3, 2023

Ọọni Ifẹ f'ọkan araalu balẹ lori iṣoro to n dojukọ Naijiria


Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi ti rọ gbogbo ọmọ Naijiria lati ṣe suuru pẹlu Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu lori bi nnkan ṣe ri lasiko yii, eto ọrọ aje, to si loun nigbagbọ pe idẹrun yoo wọ Naijiria.

Kabiyesi lo sọrọ naa laipẹ lakoko to ṣabẹwo si agboole rẹ niluu Ile-Ifẹ, lara akanṣe eto ayẹyẹ ọdun Ọlọjọ to n lọ lọwọ.

Ọọni Ifẹ, Ọjaja keji sọ pe akoko idanwo nla ni Naijiria wa lasiko yii, pẹlu awọn araalu ṣe n la oriṣiriṣi ipenija kọja ni gbogbo ẹka aye wọn.

Ninu ọrọ rẹ, Kabiyesi sọ pe 
“Mo mọ pe awọn eeyan n la oriṣiriṣi iṣoro kọja lasiko yii, to si fi han daju pe asiko ipenija ni eyi.

“Ṣugbọn mọ daju pe lẹyin ayẹyẹ ọdun Ọlọjọ yii, ohun gbogbo yoo pada bọ si ipo, nitori pe gbogbo iṣoro ti a n la kọja yoo d’opin.”

Bakan naa ni Kabiyesi parọwa si gbogbo eeyan lati rii daju pe wọn tubọ farada ohun to n ṣẹlẹ, ati pe ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu awọn adari, to si ni nipa ṣiṣe eyi, ilọsiwaju rere yoo wa.

“A ti fẹẹ de ibẹ, wura naa ni lati kọkọ la inu ina kọja ko to di pe o bẹrẹ sii dan. Ijọba nikan ko le da gbogbo rẹ ṣe lai si ifọwọsowọpọ awọn araalu”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI