Eto ilera to pe ye, alaafia ati igbayegbadun araalu lo jẹ ijọba mi logun - Gomina - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, October 31, 2023

Eto ilera to pe ye, alaafia ati igbayegbadun araalu lo jẹ ijọba mi logun - Gomina


Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe eto ikera to pe ye, alaafia ati igbayegbadun araalu lo jẹ ijọba oun logun julọ, idi ree toun fi n sa gbogbo ipa lati rii pe nnkan lọ bo ti tọ ati bo ti yẹ.

AbdulRazaq lo sọrọ naa lọjọ Ajr, Mọnde, lasiko to ṣe abẹwo oju-mi-to si ọsibitu ijọba, General Hospital to wa niluu Ilọrin lati wo bi nnkan ṣe n lọ.

Abẹwo naa lo ti wo bi awọn irinṣẹ itọju igbalode ti wọn ṣẹṣẹ ra ṣe n ṣiṣẹ si ati bi wọn ṣe n lo wọn.

O ni ko pọn dandan ki awọn eeyan maa lọ gba itọju loke okun mọ niwọn igba ti awọn irinṣẹ ayẹwo ati itọju igbalode ti wa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI