Ọpẹ́ o! Lẹ́yìn ọdún márùn-ún tí ìyàwó rẹ jáde láyé, ìyàwó tuntun bímọ fún Kasnaty l'Abẹ́òkúta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 5, 2023

Ọpẹ́ o! Lẹ́yìn ọdún márùn-ún tí ìyàwó rẹ jáde láyé, ìyàwó tuntun bímọ fún Kasnaty l'Abẹ́òkúta


Ayọ abara bintin ni awọn ololufẹ gbajugbaja ọkunrin sọrọsọrọ agbaye nni, Kọlawọle Atanda Adejojo ti ọpọ mọ si Kasnaty Sugar lori bi iyawo rẹ tuntun ṣe bimọ obinrin lantilanti.

Ọjọ Aje tii ṣe Mọnde to kọja yii, iyẹn ọgbọn ọjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2023 ni iyawo Kasnaty Sugar bimọ si ọkan lara awọn ọsibitu to gbajumọ daadaa l'Abẹokuta.

Ọjọ kẹfa, oṣu kọkanla, ọdun 2023 tii ṣe ọjọ Aje, Mọnde ni eto isọmọlorukọ yoo waye niluu Abẹokuta, olu-ilu ipinlẹ Ogun.

Bi wọn ba n darukọ awọn pedepede ati sọrọsọrọ n'ipinlẹ ti ogo wọn n tan kaakiri agbaye lasiko yii, odu ni Kasnaty Sugar, kii ṣaimọ foloko.


Bi ẹ ko ba gbagbe, ọdun marun-un sẹyin ni ọkunrin naa padanu iyawo rẹ to fẹ niṣu-lọka, Oloogbe Sẹmiat Oyindamọla Adejojo, to si jẹ pe latigba naa ni awọn eeyan ti n beere pe igba wo ni yoo fẹ iyawo miran.

Ọkunrin naa ko da ẹnikẹni lohun, ṣugbọn lara awọn to sunmọ ọn ma n sọ pe Kasnaty Sugar fẹẹ farabalẹ wa obinrin ti yoo tun dabi Ifọkanbalẹ.

Ṣugbọn ni bayii, Kasnaty Sugar ti ri ẹni bi ọkan rẹ, wọn si tun ti jọ bi ọmọ funra wọn.


Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ, gbajugbaja wolii nni, Wolii Israel Ọladele Ogundipẹ ti ọpọ mọ si Genesis ni yoo sọ ọmọ Kasnaty Sugar lorukọ niluu Abẹokuta.

Ọpọ awọn agba Wolii ati Aafa naa la tun gbọ pe wọn n bọ nibi eto ayẹyẹ isọmọlorukọ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI