Ijọba Kwara sọrọ lori ijamba ọkọ ọgba ẹwọn to waye n’Ilọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, October 20, 2023

Ijọba Kwara sọrọ lori ijamba ọkọ ọgba ẹwọn to waye n’Ilọrin


Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn ti bẹrẹ itọju ọfẹ fun gbogbo awọn to farapa ninu ijamba ọkọ ileeṣẹ ọgba ẹwọn to waye niluu Ilọrin, ipinlẹ naa.

Awọn alaṣẹ ọsibitu nipinlẹ Kwara, Kwara State Hospitals Management Board ninu atẹjade ti wọn gbe jade lọjọ Ẹti, Furaide to kọja sọ pe awọn meje ni wọn farapa ninu ijamba naa, ati pe awọn ti bẹrẹ itọju ọfẹ fun gbogbo wọn.

Ọja Ọba niluu Ilọrin ni ijamba naa ti waye, gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ti wọn si ko gbogbo wọn lọ si ọsibitu ijọba ipinlẹ naa. 

Meji ninu awọn to farapa naa la gbọ pe ara wọn ti ya, ti wọn si ti gba ile wọn lọ, nigba ti awọn yooku ṣi wa nibi ti wọn ti n gba itọju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI